Posts

Showing posts from September, 2017

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá

Image
Ó dáa ó dáa! Mo mọ̀n pé ẹ̀rọ ayárabíàṣá lorúkọ tí computer ń jẹ́ ní èdè Yorùbá. N kò jiyàn rẹ̀ rárá o. Dájúdájú gbogbo wa la ti gbà pé orúkọ rẹ̀ nìyen. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá fojú inú wòó, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe ní alẹ́ ọjọ́ kan, ẹ ó ríi pé orúkọ yìí kù díẹ̀ káà tó!

Ní alẹ́ ọjọ́ tí mo ń sọ yìí, mo tan ẹ̀rọ ayárabíàṣá mi pé kí n sáré ṣiṣẹ́ kan kíakiá kí n tó lọ sùn. Títàn tí mo tàn án tán, lóbá dí kùùrùrù, ó di kẹẹrẹrẹ. Bí ó ti ń sún kẹrẹ ni ó ń fà kẹrẹ. Nǹkan tí kò gbà ju ìsẹ́jú kan lọ tẹ́lẹ̀, ó di oun tí a ń fi ìsẹ́jú mẹ́rin ṣe. Gbogbo ẹ̀ wá ń fẹsẹ̀ falẹ̀ bí ìjàpá. Ẹ̀rọ wá di ẹ̀rọ àfìdíwọ́bíìgbín!

Àb’ẹ́ẹ̀ríǹkan? ǹjẹ́ orúkọ yìí péye mọ́n? Ótì o, èmi ò rò bẹ́ẹ̀ rárá. Nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nipé lẹ́hìn bíi ọdún méjì láti ìgbà tí ènìà bá kọ́kọ́ ra ẹ̀rọ ní títun, ẹ̀rọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́. Àwọn nǹkan inú ẹ̀rọ tí wọ́n ń mú u ṣiṣẹ́ náà a máa gbó pẹ̀lú. Àmọ́ pàápàá jùlọ, nǹkan tó fàá nipé bí àsìkò àti ìgbà ṣe ń lọ síwájú ni iṣẹ́ tí a ń fún ẹ̀rọ yìí ṣe ń ṣòro síi tí ó sì ń wúwo síi. Agb…

Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè

Image
Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kaàrún ọdú un 1953 ni Elizabeth gorí oyè. Ó wa jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba orílẹ̀èdè UK àti gbogbo àwọn ilú káàkiri àgbáyé tí wọ́n wà lábẹ́ UK nítorí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ló mú wọn sìn.

Orílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣùgbọ́n òmìnira dé fún wa ní ọdún un 1960, a sì kúrò lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ní ọjọ́ àyájọ́ ọdúnìí tó pé ọgọ́ta ọdún tí Elizabth gorí oyè, àkànṣe ńlá gidi ló jẹ́. Ọjọ́ márùn-ún gbáko ni wọ́n fi ṣe ètò ẹ̀yẹ yìí. Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì dá ọjọ́ Ìṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsimin fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n ó le r’áàyè lọ wòran níbi ayẹyẹ nlá yìí. Ṣé ọjọ́ Ajé kúkú ti jẹ́ ọjọ́ odún kan tẹ́lẹ̀, gbogbo ẹ̀ wá jẹ́ ọjọ́ mẹ́rin – Àbámẹ́ta, Aìkú, Ajé àti Iṣẹ́gun – tí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyàn r’áàyè jáde wòran dáadáa. Kódà ọ̀pọ̀ ló wá láti ọnà jíjìn àti ìdálẹ̀ láti darapọ̀ mọ́n èrò tó wá bọ̀wọ̀ fú ọba yìí.

Onírúirú àrà ní wọ́n dá o! Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọpọ́n àti ọkọ̀-ojú-omi ni wọ́n dárà lórí odò Thames fún ọjọ́ méjì. Elizabeth fúnrarẹ̀ wà nínú ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀-ojú-…

Bàtà Àràmàndà

Image
Abẹsẹ̀ gígùn mà wá dáràn o! Ẹ ní kílódé? Yó dáa fún yín!

Ṣèbí tí èyàn bá ń wá ìbọ̀sẹ̀ tàbí sòkòtò rà, èyí tó bá gùn délẹ̀ tàbí èyí to wọ̀’yàn lẹ́sẹ̀ l’èyàn ń wá? Àyàfi tí irúfẹ́ oge kan bá gbòde tójẹ́pé ṣòkòtò-ò-balẹ̀ l’olúwarẹ̀ ń kúkú wá ká. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣòkòtò ó gbọdọ̀ gùn délẹ̀ ni. Ó sì yẹ kí ààyè ó gba esè nínú u bàtà pẹ̀lú.

Ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọnsẹ̀ àwọ́n géndé, láìí ṣe t’ọmọdé, máa ń ṣábàá bẹ̀rẹ̀ láti 7 dé 12, ìyen fún génde ọkùnrin. Ìgbàmíràn èyàn tún lè rí 6 fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ kékeré, tàbí 13 (tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ) fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ gòdògbà. Tí géndé ọkùnrin mẹ́wàá bá wọn ẹsẹ̀, mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án nínu wọn ni wọ́n á bọ́sí láti 7 dé 10. Nítorí èyí ni àwọn onísọ̀ ibọ̀sẹ̀ dín iye bàtà tó ju 10 lọ kù. Báyìí, wọ́n a le rí bàtà tà dáadáa síi, nítorípé díẹ̀ náà ni iye àwọn oníbàárà wọ́n tí ẹsẹ̀ ẹ wọ́n ju 10 lọ.

Nǹkan tó fa wàhálà fún ẹlẹ́sẹ̀ ńlá rèé o! Olúwa rẹ̀ ó wá pàráàró títí yó fi sú u. Tí ẹni ọ̀hún tún bá ṣoríire tó rí ibọ̀sẹ̀ tó bẹ́sẹ̀ ẹ rẹ̀ mu, bàtà ńlá yìí ó tún ṣe …

Tiwantiwa

Image
Ẹ̀rọ ìgbàlódé tó gbajú-gbajà tí à mọ̀ sí ‘Aiyélujára’ ti s’ayédẹ̀rọ̀ báyìí o! Bí ó ti ń sọ ẹ̀rọ ayárabíàṣá di amóhùnmáwòrán ni ó ń sọ ọ́ di ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì. Kódà, ó kúkú ti sọ ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì di asọ̀rọ̀gbèsì nítorípé ó fún àwọn olùgbọ́ ètò ní àǹfàní láti dásí ètò kí wọ́n sì fèsì s'ọ́rọ̀. Àb’ẹ́ẹ̀ríǹkan?

Ètò ìgbóhùn s’áfẹ́fẹ́ kan ni mo s’àwárí ní’jọ́kan. Èdè Yorùbá ni wọ́n fi ń gbé ètò náà s’afẹ́fẹ́ fún ìgbádùn àwa elédè káàárọ̀-oòjíire. Tiwantiwa ni wọ́n ń pe ètò náà gẹ́gẹ́ bí ètò Yorùbá fún àwa Yorùbá. Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ń gbé ètò náà si afẹ́fẹ́ àmọ́ bí mo ti wí tẹ́lẹ̀, àǹfàní wà láti fetísí ètò náà káàkiri àgbáyé nípasẹ̀ ẹ́ ẹ̀ro ìgbàlódé tó ti mú ayé lujára bí ajere!

Ọjọ́ mẹ́jọ-mẹ́jọ, ìyẹn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ni ètò náà ń jáde. Onírúirú abala sì ló wà nínú ètò ọ̀hún. Àwọn àlejò jànkàn-jànkàn a sì máa ń wá sórí afẹ́fẹ́, tí wọ́n máa ń la àwọn olùgbọ́ l’óye, tí wọ́n sì máa ń dáhùn ìbéèrè wọ́n.

L’áti ìgbà tí mo ti mọ̀n nípa ètò Tiwantiwa ni n kò lè ṣàì fetísí i lọ́sọ̀…

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Image
Ní ọjọ́ mélòókan sẹ́yìn, ẹnìkan bèèrè lórí Twitter pé kí l’àá ṣe ń pe “SIM Card” ní èdè Yorùbá. Ibéèrè yìí lo múmi fẹ́ kọ àkọsílẹ̀ ránpẹ́ yìí nítoripé kò ṣeé dáhùn ní gbólóhùn kan lásán.

Yorùbá bọ̀ ó pòwe. Ó ní “ẹja l’ẹja ń jẹ sanra”. Èyìí ló dífá fún gbogbo èdè pátápátá kárí aiyé!
Àlàyé òwe yìí ni pé eja ni èdè. Èdè míràn sì ni èdè ń mú mọ́ra kí ó fi gbòòrò síi, ìyẹn nípasẹ̀ èdè-àyálò. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí fún gbogbo èdè l’áyé.

Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ ṣe àtúpalẹ̀ orúkọ “SIM Card” yìí. SIM Card ni nǹkan kékeré kan tó wà nínu ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èròjà ti ń mú ẹ̀rọ náa ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí SIM Card ń ṣẹ ni pé òun ló jẹ́ nǹkan ìdánimọ̀ nínu ẹ̀rọ yìí. SIM Card yìí ni Ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fi ń dá alágbèéká kọ̀ọ̀kan mọ̀n yàtọ̀ sí arawọn.

Ike pẹlẹbẹ tí kò tóbi ju bí èkana ọwọ́ lọ ni. Wón sì fi irin ṣe àmì sí ojúkan ike yìí. Inú àmì irin yìí ni wọ́n fi orísìírísìí nǹkan pamọ́n sí. Ọgbọ́n àti òye ìgbàlódé ni gbogbo èyí jẹ́ tó sì dàbí idán lójú aláìmòye.

Orúkọ “SI…

Aworẹrin

Image
Ní ọjọ́ kàn báyìí tí mò ń wá nǹkan kà ní èdè Yorùbá ni mo ṣ’àwàrí kiníkan lórí aiyélujára ìtàkùn-àgbáyé. Aworẹrin l’orúkọ nǹkan náà. Aworẹrin yìí dàbí i ìwé ìròhìn olóṣooṣù ṣùgbọ́n dípò ìròhìn ó kún fún orísìírísìí nǹkan bí i àròkọ, àwòrán, ìtàn, òwe, ààlọ́, orin, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ ní http://www.aworerin.com àwọn kan ni wọ́n ṣe akitiyan àti gbé ìwé yìí jáde lórí fún ànfàní gbogbo àwa olólùfẹ́ èdè káàárọ̀-oòjíire. Ọdún un 1940 àbí nǹkan ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé yìí jáde ní Nàìjíríà ṣùgbọ́n wọ́n dáwọ́ ẹ̀ dúró ní nǹkan bí i 1980. Ìyẹn ni pé bí ogójì ọdún gbáko ni wọ́n fi tẹ̀ẹ́ jáde lóṣooṣù. Bí a bá ṣe ìṣirò ránpẹ́: Oṣù méjìlá lọ́dún lọ́nà ogójì, ó jẹ́ ọgọ́rùún mẹ́rin àti ọgọ́rin.

Àmọ́ ẹyọ iwé Aworẹrin méjì péré ló wà lórí ìbùdó ọ̀hún o. Èyí jẹ́ ìjákulẹ̀ fún mi nítorípé mo gbádùn kíka àwọn nkan inú ìwé yìí gidi-gidi. Inú ù mí dùn pé wọ́n ṣe ìlérí lórí ìbùdó o wọ́n pé iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ takuntakun láti kó gbogbo àwọn ìwé yìí jọ fún gbígbé jáde lóri aiyélujá…

Oúnjẹ Àárọ̀ Ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Image
Ọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa oúnjẹ àárọ̀ tí wọ́n máa ń jẹ ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Pàápàá jùlọ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ọjọ́ ìsinmin àbámẹ́ta àti àìkú. Ìyen ni òpin ọ̀sẹ̀ tí kò l’áàánsáré jẹun kí a le tètè jáde nílé lọ ibiṣẹ́ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.

N kò lè s’àì mẹ́nuba oúnjẹ oní kíákíá tí ó wọ́pọ̀ láti jẹ lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀. Èyí tó wọ́pọ̀ jùlọ ni kiní kan tí wọ́n fi àgbàdo àbí ọkà-bàbà ṣe tí wọ́n ń pè ni cornflakes. Bí wọ́n ti ń jẹ oúnjẹ àgbàdo yìí lèyìí. Wọ́n a dàá sí inú àwo, wọ́n a sì da wàrà tútù lé e. Òmíràn nínú àwọn oújẹ àgàdo yìí ni wọ́n á ti fi ṣúgà tàbí oyin àti onírúirú nǹkan aládùn pa lára. Ṣùgbọ́n òmíràn a máa jẹ́ gberefu.

Nígbàmíràn tí kò bá si oúnjẹ nílé, wọ́n a máa ra oúnjẹ àárọ̀ aláràjẹ lọ́nà. l’áràárọ̀ ni èrò máa ń tò síwájú àwọn ilé oúnjẹ wọ́nyìí tí wọ́n sì njẹ àjẹrìn dé ibiṣẹ́.

Eléyìí tí wọ́n ń farabalẹ̀ jẹ, tí wọ́n sì fẹ́ràn gidi jùlọ ni wọ́n ń pè ní Ọúnjẹ Àárọ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Oúnjẹ yìí lékenkà tóbẹ́ẹ̀gẹ́ ó sì jẹ́ nǹkan ìwúrí fún orílẹ̀èdè yìí. Orísìírísìí ẹ̀yà oúnjẹ yìí ni ó w…

Ìrìnàjò lọ sí òkè òkúta Robin Hood

Image
Èyí ni ìrìnàjò lọ sí òkè òkúta Robin Hood. Ilẹ̀ ẹ Gẹ̀ẹ́sì ni òkúta náà wà ní ẹ̀ bá igbó nlá kan.  Ọpọ̀ lọpọ̀ abúlé àti ìgbèríko ni wọ́n yí igbó àti òkúta yìí ká. Ọ̀̀kan nínú àwọn abúlé náà ni Youlegrave. Tí a bá pe ìrìnàjò náà ní ìrìnkèrindò, a kò parọ́ rárá! Nítorípé láti abúlée Youlegave dé òkúta Robin Hood, bí arìrìnàjò bá ṣe ń pọ́́n òkè náà ni yó ṣe máa sọdá afárá kọjá àwọn odò kékèké.  Bí ènìà dẹ̀ ṣẹ ń pàdé ehoro náà ni olúwarẹ̀ á máà rí onírúirú ẹiyẹ tí wọ́n ń fò káàkiri láti igi sí igi inú igbó. Bẹ́ẹ̀ náàni ènìà á tún máa láti fo àwọn odi kékèké tí àwọn onílẹ̀ kọ́ yí ilẹ̀ wọn po. Àwọn odi wọ̀nyí jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìfàlà sílẹ̀ tí àwọn onílẹ̀ yìí fi dá ilẹ̀ tiwọn yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn. Youlegrave ni abúlé tí ìrìnàjò yìí ti bẹ̀rẹ̀ . Ó ti pé bíi ọgọ́rùún mẹ́sàán ọdún ti àwọn ènìà ti ń gbé abúlé yìí. Gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà níbẹ̀ pátápátá ni wọ́n fi òkúta kọ́. Kò dẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn ilé wọ̀nyí tí wọ́n kùn lọ́dà rárá. Èyí mú kí gbogbo àwọn ilé yìí báramu dáadáa kí wọ́n sì gú…

Mojúbà o!

Image
Yorùbá bọ̀ ó pòwe. Ó ní "Ẹ jẹ́ ká ṣeé bí wọ́n ti n ṣeé kó lè báà rí bí ó tí n rí". Nítorínáà ẹ jẹ́ kí n fìbà f'óníbà, kí n fọpẹ́ fún ọlọ́pẹ́. Mojúbà Ọlọ́run Olófin Olódùmarè ọba àkọ́dá aiyé aṣẹ̀dá ọ̀run. Arúgbó ọjọ́ Adàgbàmápààrọ̀oyè Káábíèsí o! Mojúbà àwọn òbí mi bàbá àti ìyá mi. Ẹkú ìgbìyànjú. Mojúbà gbogbo ẹbí lọ́kùnrin lóbìnrin lọ́mọdé lágbà. Mojúbà gbogbo ọ̀rẹ́ pèlú. Mojúbà gbogbo aṣájú ọ̀mọ̀wé, ọ̀jọ̀gbọ́n, amòye àti olùkọ́ èdè Yorùbá pátápátá. Ẹ jẹ́ kó yẹ mí o ìbà ni mo ṣe.