Posts

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Image
Ẹkú ọjọ́ mẹ́ta o ẹ̀yin ènìà pàtàkì wọ̀nyí. Ṣe dáradára ni mo bá gbogbo yín o?
Ọ̀rọ̀ ọ t'òní á fẹ́ jọ yẹ̀yẹ́ létí ẹlòmíì, ṣùgbọ́n kìí ṣ'àwàdà rárá o. Ọ̀rọ̀ gidi ni.

Ẹ ní kílódé? Ẹ mà ṣeun o. Ebi ló pa mí ní ìrọ̀lẹ́ òní tó mún mi ya ilé oúnjẹ olókìkí nì tí wọ́n ń pè ní KFC. Adìẹ díndín ni wọ́n ń tà níbẹ̀. 'Tapátẹsẹ̀ ni wọ́n ń dín in. Tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́ ní ẹyọ-ẹyọ, ẹ lè rà á bẹ́ẹ̀. Bó sì jẹ́ àdàpọ̀ ẹsẹ̀ àti apá lẹ fẹ́, ìyẹn náà wà. Kódà wọn a tún máa ṣè'kan pẹlẹbẹ láti igbá-àyà adìẹ, wọ́n á tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ sí ààrin búrẹ́dì pẹ̀lú ẹ̀fọ́ díẹ̀ àti àwọn midinmíìdìn ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Àwọn olóyìnbó a máa pè'yẹn ní "Burger". Kiní ọ̀hún a máa wù'yàn jẹ o jàre. Àgàgà àwọn tí wọ́n fi ata sí dáadáa. Wọ́n tún ṣe'kan tó jọ dùndú anọ̀mọ́ tí wọ́n ń pè ní "fries". Kiní ọ̀hún a máa dùn tí wọ́n bá dín in gbẹ dáadáa. Parí-par…

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Image
Ṣé mo sọ níjọ́sí pé ìfẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bímọ. Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà ọmọ tí wọ́n bí ju ẹyọ kan ṣoṣo lo. Àwọn ọmọ náà ni Ààrùn, Àìsàn, Àìlera àti Àárẹ̀.

Àwọn ọmọ wọ̀nyí a máa farahàn ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrà, wọn a sì máa da ọmọ-ènìyàn l'áàmú. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà àrà náà nìwọ̀nyí;

Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìfúnpá Gíga, Ìtọ̀ Ṣúgà, Wárápá, Àìsàn Ọkàn, Ọpọlọ Wíwú, Ojú Fífọ́, Ìdákọ́lẹ, Àpọ̀jù Ọ̀rá-Ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Abí ẹ kò rí i pé àjẹjù ṣúgà kò dára fún ọmọ ènìyàn rárá bí? Ó yẹ ká yẹra fún un nígbà gbogbo, kí ó má baà ṣe àkóbá fún wa.

Toò, ẹ jẹ́ ká fi man báhun lónìí nítorí pé "ṣókí l'ọbẹ̀ oge". Èmi ni Alákọ̀wé yín ọ̀wọ́n. Ó tún dìgbà kan ná.

Ènìyàn àti Ṣúgà

Image
Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé "a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́". Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé.

Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe.

Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá.

Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo - ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá àyè wa. A n…

Ìtẹ̀wé Yorùbá titun gbòde

Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin tèmi. Ó tójọ́ mẹ́ta kan. Ǹjẹ́ ẹ rántí ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, mo ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà kọ èdè Yorùbá pẹ̀lú àmì lórí àwọn ẹ̀rọ wa.


Ọ̀nà titun kan ti balẹ̀ wàyí o! Yorubaname.com ni wọ́n fún wa ní ẹ̀bùn yí ní ọ̀fẹ́.

Mo ti ń ṣe àmúlò ìtẹ̀wé yìí ní kété tó jáde, kí n lè fún un yín lábọ̀ nípa rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ṣòro ó lò lákọ̀ọ́kọ́, nítorí kò mọ́n mi lára, kò pẹ́ náà tó fi mọ́nra. Kódà, òun ni mò ń lò lọ́wọ́ báyìí.

Díẹ̀ nínú àwọn àǹfàní tọ́n hàn sí mi nìwọ̀nyí:

1. Àyè àti fi àmì sí 'n' àti 'm' ( ǹ ń, m̀ ḿ )
2. Ó ń ṣiṣẹ́ lórí Windows àti Mac
3. Kò l'áàńsí lórí Ayélujára láti ṣiṣẹ́
4. Ó rọrùn láti lò púpọ̀ ju àwọn ìyókù lọ, tí ó bá ti móni lára tán.
5. Ọ̀fẹ́ ni!

Ajẹ́pé ẹ jẹ́ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Yorubaname.com fún akitiyan ńlá yìí. Ó dámi lójú pé èyí kò ní ṣe àṣemọn wọn o. Lágb…

Ata ju ata lọ

Image
Ẹ wá wo orí ológbò látẹ o ẹ̀yin èèyàn mi! "Èwo lẹ tún rí o Alákọ̀wé?" Yó yẹ yín kalẹ́! Mo mà tún rí nkan o.

Lóòótọ́ àwa ọmọ Nàìjá a fẹ́ran ata, àgàgà àwa ti ilẹ̀ Oòduà. Ẹlòmíì a se'bẹ̀, a fi ata já a. Kódà a rí ẹni tí kò ní jẹun kankan àfi tí ata bá wà níbẹ̀. Dájú-dájú ìran jata-jata ni àwa ń ṣe.

Òun ni mo fi ń yangàn fún àwọn ọ̀rẹ mi kan nílẹ̀ yìí o. Mo wí fún wọn pé kòsí oúnjẹ kankan nílẹ̀ wọn tó láta to tiwa. Mo tún ṣakọ pé irúfẹ́ ata tí èmi Alákọ̀wé ò lè jẹ - wọn kò tí ì ṣẹ̀dá ẹ̀ nílẹ̀ yìí.

Àwọn òyìnbó dá mi lóhùn pé òtítọ pọ́nbélé ni mo sọ, n kò parọ́ rárá.   Wọ́n tún wípé kódà àwọn aláwọ̀ funfun tí mo rí yìí - tí àwọn bá ṣèṣì jẹ irú ata tí a ń wí yìí, ńṣe ni ojú àwọn á di pípọ́n kuku bí aṣọ àparò! Bẹ́ẹ̀náàni gbogbo ọ̀nàfun á máa ta àwọn bí ẹní máa kú ni. Wọ́n ní nítorí ìdí èyí ni àwọn kò ṣe kí ń jẹ ata. Pé tí oúnjẹ bá ti láta fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ báyìí, àwọn a yáa yẹra fún un.  Mo rín ẹ̀rín àrínbomilójú nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí tán. Kání àwọn babańlá wa mọ̀n níjọ́ kìíní à…

Pàtàkì Ìwé Kíkọ Àti Kíkà Ní Èdè Abínibí

Image
Oun tí a ní là ń náání. Àwọn àgbà Yorùbá ni wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ ní òde òni àwa ọmọ Odùduwà ń náání oun tiwa bí? Ọ̀rọ̀ ọ́ pọ̀ níbẹ̀ o ẹ̀yin ará mi. Ó dáa ẹ jẹ́ ká mú'kan níbẹ̀ ká gbé e yẹ̀wò.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ràn láti máa sọ èdè Yorùbá lẹ́nu mọ́n, dájú-dájú púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí gbọ́ ọ l'ágbọ̀ọ́yé, wọn kò kàn kí ń sọ ọ́ ni.

Lára àwọn agbọ́másọ wọ̀nyí, bóyá la lè rí ìkankan nínú wọn tó mọn èdè Yorùbá kà dáradára, ká tilẹ̀ má sọ̀rọ̀ ọ kíkọ. Àgàgà tí a bá fi àmì sọ́rọ̀, a máa fa ìrújú fún púpọ̀ nínú wọn. Ó mú mi rántí nkan tí ẹnìkan wí lóri Twitter níjọ́sí. Ó ní Yorùbá kíkọ̀ èmi Alákọ̀wé fẹ́ jọ èdè Lárúbáwá lójú òun nítorí àwọn àmì ọ̀rọ̀ tí mo máa ń fi sí i. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún pa mí ní ẹ̀rin lọ́jọ́ náà kì í ṣe díẹ̀.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ burúkú òhun ẹ̀rín kọ́ rèé ni ẹ̀yin èèyàn mi? À á ti wá gbọ́? Ṣé ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípà èdè Gẹ̀ẹ́sì kíkọ? Ótì o! Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àbí ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Faransé ti ń ránmú sọ Faransé bí? Èmi ò rí i rí o.


Kí ló wá fà á?…

Ebola

Image
Mo kí gbogbo yín o. Ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ẹ sì kú àìfaraálẹ̀ náà. Olúwa yó máa fúnwa ní alékún okun àti agbára o.

Toò, ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò wá. Èé ti rí? Ọ̀rọ̀ Ebola yìí mà ni o. Kòkòrò búburú tí í fa àjàkálẹ̀ ààrùn. Kòkòrò tí kò gbóògùn.

Bóo la ti wá fẹ́ ṣe é o? Ibo là á gbe gbà? Àwọn oní Bókobòko níwá, Èbólà lẹ́hìn. Àfi kí Elédùà kówa yọ.

Àmọ́ ṣá, Yoòbá ti wípé ojú l'alákàn fi ń ṣọ́rí. Kí oníkálukú yáa tẹra mọ́n ètò ìmọ́ntótó rẹ̀. Kí ó sì máa ṣe àkíyèsí gbogbo nkan tí ń lọ ní'tòsí.

Orísìírísìí là ń gbọ́ nípa kí la lè ṣe láti dáàbò bo'ra ẹni. Àwọn kan ní omi gbígbóná àti iyọ̀ ni ká fi wẹ̀. Kíá ni àti mùsùlùmí àti kìrìstẹ́nì ń da omígbóná ságbárí. A tún gbọ́ pé orógbó tàbí obì ni àjẹsára tọ́n lè báni yẹra fún ààrùn Ebola. Wéré ni tọ́mọ́ndé tàgbà ń rún orógbó lẹ́nu bí i gúgúrú, tí wọ́n sì ń jẹ obì bí ẹní jẹ̀pà. Àt'orógbó àt'obì o, wọn ò ṣé rà lọ́jà mọ́n, ńṣe ni wọ́n gbówó lérí tete.

Bẹ́ẹ̀ rèé ènìyàn ò báà bẹ́ sínú àmù ọmígbóná oníyọ̀, kó jẹ́ orógbó agbọ̀n kan, kó sì jẹ…