AworẹrinNí ọjọ́ kàn báyìí tí mò ń wá nǹkan kà ní èdè Yorùbá ni mo ṣ’àwàrí kiníkan lórí aiyélujára ìtàkùn-àgbáyé. Aworẹrin l’orúkọ nǹkan náà. Aworẹrin yìí dàbí i ìwé ìròhìn olóṣooṣù ṣùgbọ́n dípò ìròhìn ó kún fún orísìírísìí nǹkan bí i àròkọ, àwòrán, ìtàn, òwe, ààlọ́, orin, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ ní http://www.aworerin.com àwọn kan ni wọ́n ṣe akitiyan àti gbé ìwé yìí jáde lórí fún ànfàní gbogbo àwa olólùfẹ́ èdè káàárọ̀-oòjíire. Ọdún un 1940 àbí nǹkan ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé yìí jáde ní Nàìjíríà ṣùgbọ́n wọ́n dáwọ́ ẹ̀ dúró ní nǹkan bí i 1980. Ìyẹn ni pé bí ogójì ọdún gbáko ni wọ́n fi tẹ̀ẹ́ jáde lóṣooṣù. Bí a bá ṣe ìṣirò ránpẹ́: Oṣù méjìlá lọ́dún lọ́nà ogójì, ó jẹ́ ọgọ́rùún mẹ́rin àti ọgọ́rin.

Àmọ́ ẹyọ iwé Aworẹrin méjì péré ló wà lórí ìbùdó ọ̀hún o. Èyí jẹ́ ìjákulẹ̀ fún mi nítorípé mo gbádùn kíka àwọn nkan inú ìwé yìí gidi-gidi. Inú ù mí dùn pé wọ́n ṣe ìlérí lórí ìbùdó o wọ́n pé iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ takuntakun láti kó gbogbo àwọn ìwé yìí jọ fún gbígbé jáde lóri aiyélujára ìtàkùn-àgbáyé. Bíotilẹ̀jẹ́pé ẹyọ méjì náà lọwọ́ wà tẹ̀ níbẹ̀, ó dùn ún kà ó sì tún dá’ni lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú!

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá

Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè