Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?


Ní ọjọ́ mélòókan sẹ́yìn, ẹnìkan bèèrè lórí Twitter pé kí l’àá ṣe ń pe “SIM Card” ní èdè Yorùbá. Ibéèrè yìí lo múmi fẹ́ kọ àkọsílẹ̀ ránpẹ́ yìí nítoripé kò ṣeé dáhùn ní gbólóhùn kan lásán.

Yorùbá bọ̀ ó pòwe. Ó ní “ẹja l’ẹja ń jẹ sanra”. Èyìí ló dífá fún gbogbo èdè pátápátá kárí aiyé!
Àlàyé òwe yìí ni pé eja ni èdè. Èdè míràn sì ni èdè ń mú mọ́ra kí ó fi gbòòrò síi, ìyẹn nípasẹ̀ èdè-àyálò. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí fún gbogbo èdè l’áyé.

Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ ṣe àtúpalẹ̀ orúkọ “SIM Card” yìí. SIM Card ni nǹkan kékeré kan tó wà nínu ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èròjà ti ń mú ẹ̀rọ náa ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí SIM Card ń ṣẹ ni pé òun ló jẹ́ nǹkan ìdánimọ̀ nínu ẹ̀rọ yìí. SIM Card yìí ni Ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fi ń dá alágbèéká kọ̀ọ̀kan mọ̀n yàtọ̀ sí arawọn.

Ike pẹlẹbẹ tí kò tóbi ju bí èkana ọwọ́ lọ ni. Wón sì fi irin ṣe àmì sí ojúkan ike yìí. Inú àmì irin yìí ni wọ́n fi orísìírísìí nǹkan pamọ́n sí. Ọgbọ́n àti òye ìgbàlódé ni gbogbo èyí jẹ́ tó sì dàbí idán lójú aláìmòye.

Orúkọ “SIM Card” yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹyọọ̀kan ṣoṣo o, ọ̀rọ̀ mẹ́rin ni wọ́n mú pọ̀, tí wọ́n tún wá gé e kúrú. “Subscriber Identifier Module Card” gangan ni orúkọ rẹ̀ lẹ́kùúnrẹ́rẹ́. SIM jẹ́ lẹ́tà kíní tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mẹ́tẹ̀ta àkọ́kọ́. “Acronym” ni wọ́n ń pe gígé ọ̀rọ̀ kúrú báyìí ní Gẹ̀ẹ́sì.

Ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yọ kọ̀ọkan rèé

Subscriber: Onílò
Identity: Ìdánimọ̀
Module: Ẹyọ
Card: Ike/Páálí

Tí a bá lo irú ìsọǹkanlórúkọ yìí, a lè pèé ní “Ike Ẹyọ Ìdánimọ̀ Onílò”, ká tún gée kúrú sí “Ike EIO”. Sùgbọ́n irú orúkọ yìí ò bójúmu, kò sì nítumọ̀ kankan ní Yorùbá.

Nkan ìgbàlódé ni SIM Card jẹ́. Ní ọdún 1991 ní orílẹ̀èdè Jamaní ni wọ́n ti ṣẹ̀dá ẹ̀. Ìyẹn bí ogún ọdún àti díẹ̀ sẹ́yìn báyìí. Àwọn tí wọ́n ṣe é náà sì ni wọ́n fún-un lórúkọ l’édè Jamaní àti Gẹ̀ẹ́sì. Èdè wa ò kópa kankan rárá nínú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Nítorínáà, a kò ní orúkọ Yorùbá pọnbélé kankan fún-un. Bẹ́ẹ̀náàni fún gbogbo èdè káàkiri àgbáíyé!

Gégé bí òwe tí mo pa níbẹ̀rè, èdè àyálò náà lókù nítorípé “ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ni ò jẹ́ ká pe àgbà ní wèrè”

Kíni ìtumọ̀ “SIM Card” l’édè Yorùbá? Símú Kaàdì.  Lóbátán.

Ẹ tẹ̀lé mi lori Twitter –> @alakoweyoruba

Comments

Post a comment

Popular posts from this blog

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá