Tiwantiwa


Ẹ̀rọ ìgbàlódé tó gbajú-gbajà tí à mọ̀ sí ‘Aiyélujára’ ti s’ayédẹ̀rọ̀ báyìí o! Bí ó ti ń sọ ẹ̀rọ ayárabíàṣá di amóhùnmáwòrán ni ó ń sọ ọ́ di ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì. Kódà, ó kúkú ti sọ ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì di asọ̀rọ̀gbèsì nítorípé ó fún àwọn olùgbọ́ ètò ní àǹfàní láti dásí ètò kí wọ́n sì fèsì s'ọ́rọ̀. Àb’ẹ́ẹ̀ríǹkan?

Ètò ìgbóhùn s’áfẹ́fẹ́ kan ni mo s’àwárí ní’jọ́kan. Èdè Yorùbá ni wọ́n fi ń gbé ètò náà s’afẹ́fẹ́ fún ìgbádùn àwa elédè káàárọ̀-oòjíire. Tiwantiwa ni wọ́n ń pe ètò náà gẹ́gẹ́ bí ètò Yorùbá fún àwa Yorùbá. Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ń gbé ètò náà si afẹ́fẹ́ àmọ́ bí mo ti wí tẹ́lẹ̀, àǹfàní wà láti fetísí ètò náà káàkiri àgbáyé nípasẹ̀ ẹ́ ẹ̀ro ìgbàlódé tó ti mú ayé lujára bí ajere!

Ọjọ́ mẹ́jọ-mẹ́jọ, ìyẹn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ni ètò náà ń jáde. Onírúirú abala sì ló wà nínú ètò ọ̀hún. Àwọn àlejò jànkàn-jànkàn a sì máa ń wá sórí afẹ́fẹ́, tí wọ́n máa ń la àwọn olùgbọ́ l’óye, tí wọ́n sì máa ń dáhùn ìbéèrè wọ́n.

L’áti ìgbà tí mo ti mọ̀n nípa ètò Tiwantiwa ni n kò lè ṣàì fetísí i lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! Ògbóòntarìgì sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni olóòtú ètò náà jẹ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oyèkúnlé Azeez. Yoòbá ẹnu ọ̀gbẹ́ni náà dùn léti bí orin ewì ni. Alàgbà Mábayọ̀jẹ́ ńkọ́? Àwọn ni wọn dúró bí i àgbàlagbà amòye tí wọ́n máa ń sàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kẹ̀nkẹ̀ ọ̀rọ̀ àgbà. Oníròhìn ná wà tí ń jẹ́ Sẹ̀san Fáfiólú tí wọ́n ń ṣe atótó arére sí etí ìgbọ́ wa. Bẹ́ẹ̀náàni Ìyá oge ọlọ́wọ́ ọ síbí ti orúkọ́ wọ́n ń jẹ́ Tóyìn Sùlàìmán. Ìyá yìí a máa ṣe àlàyé síse oúnjẹ ọlọ́kanòjọ̀kan.

Ètò yìí jẹ́ nǹkan ayọ̀ àti ìwúrí fún mi gidi gẹ́gẹ́ bí ọmọ Oòduà. Àdúrà mi ni pé kí Olódùmarè sọ agbára wọ́n di ọ̀tun. Iwáju iwájú ni ọ̀pá ẹ̀bìtì ń ré sí o!

Àṣẹ

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?