Ìrìnàjò lọ sí òkè òkúta Robin Hood


Èyí ni ìrìnàjò lọ sí òkè òkúta Robin Hood. Ilẹ̀ ẹ Gẹ̀ẹ́sì ni òkúta náà wà ní ẹ̀ bá igbó nlá kan.  Ọpọ̀ lọpọ̀ abúlé àti ìgbèríko ni wọ́n yí igbó àti òkúta yìí ká. Ọ̀̀kan nínú àwọn abúlé náà ni Youlegrave.
Tí a bá pe ìrìnàjò náà ní ìrìnkèrindò, a kò parọ́ rárá! Nítorípé láti abúlée Youlegave dé òkúta Robin Hood, bí arìrìnàjò bá ṣe ń pọ́́n òkè náà ni yó ṣe máa sọdá afárá kọjá àwọn odò kékèké.  Bí ènìà dẹ̀ ṣẹ ń pàdé ehoro náà ni olúwarẹ̀ á máà rí onírúirú ẹiyẹ tí wọ́n ń fò káàkiri láti igi sí igi inú igbó. Bẹ́ẹ̀ náàni ènìà á tún máa láti fo àwọn odi kékèké tí àwọn onílẹ̀ kọ́ yí ilẹ̀ wọn po. Àwọn odi wọ̀nyí jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìfàlà sílẹ̀ tí àwọn onílẹ̀ yìí fi dá ilẹ̀ tiwọn yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn.
Youlegrave ni abúlé tí ìrìnàjò yìí ti bẹ̀rẹ̀ . Ó ti pé bíi ọgọ́rùún mẹ́sàán ọdún ti àwọn ènìà ti ń gbé abúlé yìí. Gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà níbẹ̀ pátápátá ni wọ́n fi òkúta kọ́. Kò dẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn ilé wọ̀nyí tí wọ́n kùn lọ́dà rárá. Èyí mú kí gbogbo àwọn ilé yìí báramu dáadáa kí wọ́n sì gúnrégé. Àwọn ará abúlé náà sì jẹ́ onímọ̀ọ́tótó gbáà. Abúlé ọ̀hún dára púpọ̀ , àwọn ènìà ibẹ̀ sì fanimọ́ra gidigidi. Bí wọ́n ṣe nkí aráàlú ni wọ́n nkí àjèjì.
Àwọn ọ̀nà tí ó wà láàrin abúlé yìí ṣẹ tóóró-tóóró ni, wọn kò fẹ̀ rárá. Kódà ipá ni ọkọ̀ méjì ṣe ń gba ẹ̀gbẹ́ arawọn kọjá. Tí ọkọ̀ méjì bá pàdé arawọn báyìí, ọ̀kan nínú u wọn gbọdọ̀ dúró sí ẹ̀gbẹ́ kan kí ó yọ̀nda ọ̀nà fún èkejì láti kọjá. Ìdí èyí ni pé ní aiyé àtijọ́ nígbàtí irú àwọn abúlé yìí fìdí múlẹ̀, ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni àwọn ṣe ọ̀nà fún.
Ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ ni àwọn ará abúlé náà. Ilé-ìjọsìn nlá kan wà láàrin abúlé gangan. Ilé-ìjọsìn náà ga sókè sooroso tóbẹ́ẹ̀gẹ́ , àwọn ará ìlú míràn lè ríi lókèrè. Ẹ̀yìn Ilé-ìjọsìn yìí ni ọ̀nà tí ènìàá lè gbà jáde kúrò nínú abúlé, kí ó sì bẹ̀ rẹ̀ ìrìnàjòo lo sí òkè àpáta Robin Hood. Ṣùgbọ́n ènià á kọ́kọ́ pọ́n òkè kékeré kan ná. Ní orí òkè yìí ènìà á rí ibìkan tí àwọn àgbẹ̀ ilú ń rọ́ imíi màlúù sí. Ó dàbí wípé ajílẹ̀ ni wọ́n ń fi ìgbẹ́ẹ màlúù yí ṣẹ nítorípé ìgbẹ́ ọ̀hún pọ̀ púpọ̀ tí wọ́n rọ́ sí ojúkan. Òórùn rẹ̀ sì gbalẹ̀ gidi-gidi. Tí ènìà bá sì wo àyíká ńṣẹ ni wọ́n fán imíi màlúù yìí káàkiri gbogbo ilẹ̀ kí koríko fi lè hù dáadáa. Oúnjẹ koríko ni ìgbẹ́ eranko jẹ́ . Tí koríko náà bá hù tán, òun náà di oúnjẹ eranko. Ó dàbí òwe Yorùbá kan "Ọwọ́ kò ní lọ sẹ́nu kó má padà".
Tí ènìà bá rìn díẹ̀ kọjá orí òkè kékeré yìí dé ibi èbá odi tí ó yí pápá onígbẹ̀ẹ ́yìí po, ènìà ní láti fo odi ọ̀hún kọ̀já sí òdì kejì kí ènìà tó lè tẹ̀ síwájú. Irú òkúta tí wọ́n fi kọ́ gbogbo àwọn ilé abúlé náà ni wọ́n tò lé arawọn tí odi fi ga díè tí ó jẹ́ pé àgùntàn àbí màlúù kankan ò lè fòó kọjá sí òdì kejì. Àwọn odi kọ̀ọ̀kan ní ààyè tóóró tí ènìà lè rọra rìn kọjá láì fo odi ọ̀hún, tí kò sì gba eranko kankan. Bẹ́ẹ̀náàni àwọn àgbẹ̀ míràn ṣẹ ọ̀nà tí ó gba ọkọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ ìlèkùn-ẹranòjẹ sí ẹnu àwọn ọ̀nà wọ̀nyí tí wọ́n wà ní títì ní gbogboògbà tí wọn kò sí ní lílò. Bíbẹ́ẹ̀kọ́ gbogbo àwọn eranko ìsìn wọn, ti àgùntàn ti màlúù, ò bá sálọ tán.
Gbogbo ilẹ̀ẹ wọ́n ni àwọn onílẹ̀ fi odi yípo. Nítorínáà ènìà ní látimáà fo àwọn odi wọ̀nyìí kọjá nígbà kọ̀ọ̀kan. Àwọn onílẹ̀ yìí sì ti gba ènìà láàyè àti rìn lórí ilẹ̀ ẹ wọn láì ṣẹ̀ṣẹ̀ tú máà tọọrọ àyè lọ́wọ́ ọ wọn.  Tí ènìà bá ti fo odi mélòó kan ènìà á sọ̀ kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, á sì rìn kan odò kékeré. Odò yìí ni wọ́n ń pè ní odò o Bradford.
Omi odò yìí mọ́n tóní-tóní bí enipé ó ṣeé mu ni. Inú àpáta nlá kan ni orísun odò náà wà. Àwọn ará àwọn ilú tí wọ́n wà ní ìtòsí odò náà máa ń wá sí etí odò náà. Àwon àgbà a máa gba atẹ́gùn àláfíà sára. Bẹ́ẹ̀ni àwọn ọmọdé a máa ṣeré ká nígbàmíràn pẹlú ajá a wọn. Kò sí ẹja kankan nínú odò yìí rárá ṣùgbọ́n oríṣìíríṣìí ẹiyẹ ojú omi bíi pẹ́pẹ́íyẹ ni wọ́n bà sí ojú omi odò náà.  Etí odò yìí ni enìà ní láti tọ̀ títí dé inú igbó kan. Afárá kan wà ní ibi tí odò àti igbó ti pàdé. Ènìà ní láti sọdá afárá yìí kọjá sí ọ̀nà tí ó wọ inú igbó lọ.
Igbó nlá ni igbó náà jẹ́. Ṣùgbọ́n ìjọba ìpínlẹ̀ Derbyshire ti la ọ̀nà káàkiri rẹ̀. Ìdí tí wọ́n fi la àwọn ọ̀nà wọ̀nyìí ni pé inú igbó yìí ṣẹ pàtàkì fún àwọn ará ìpínlẹ̀ òhún gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àfẹsẹ̀rìn láti ìlúdélùú. Ẹ̀yí mú ìrìnàjò nínú igbó náà rọrùn púpọ̀. Ẹ̀nìà ní láti tọ ọ̀nà tààrà tó wà létí odò títí dé òpin rẹ̀ kí ó tó tún sọdá afárá kọjá odò. Ní ibẹ̀ ni odò náà ti kọjú sí ibòmíràn.
Oríṣìíríṣìí eranko ni ó wà nínú igbó náà. Ìjọba àpápọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ṣẹ ètò àti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko sí inú igbó nlá káàkiri ìlú. Ìdí èyí ni pé kí wọ́n wà ní òmìnira kí wọ́n sì darapọ̀ mọ́n àwọn ẹranko ìyókù nínú igbó. Ó súwọ̀n kí àwọn eranko àti ẹiyẹ wọ̀nyí máa bí síi kí wọ́n sì máa rẹ̀ síi dípò kí wọ́n wà ní àtìmọ́lé ọmọ ènìà.  Irú àwọn eranko àti ẹiyẹ tí ènìà lè rìnàkò nínú igbó náà ni ehoro, ọ̀kẹ́rẹ́, ọ̀yà, pẹ́pẹ́íyẹ, ọ̀kín, àparò, ẹiyẹlé, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. Kò sí ẹranko búburú kankan nínú igbó ọ̀hún àyàfi àwọn kòkòrò bí agbọ́n àbí àkekèé nìkan.
Oun kan ni ojú rí nínú igbó náà tí ó pani lẹ́rìín púpọ̀.  Àwọn igi kọ̀ọ̀kan wà tí àwọn ẹnìkan ya àworán sí lára. Ọ̀míràn dàbí iṣẹ́ ẹ bàsèjẹ́ àti ọmọọ̀ta. Ṣùgbọ́n ọ̀míràn dàbí iṣẹ́-ọnà gidi tí ó sì dùn-ún wò dáadáa.  Àwòrán kan wà tí ó lè ba ẹlòmíràn lẹ́rù.  Àwòrán náà dàbí orí abàmì ènìà kan tí ó ranjú kalẹ̀.  Ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú nǹkan báyìí lè rò pé iwin inú igi ló yọ sí òun ni!  Ṣùgbọ́n fún ẹni tí ó ní ìgboyà, àwòrẹ́rìín ni eléyìí jẹ́. Kódà ó mú ìrìnàjò inú igbó náà dùn dáadáa ni.
Ní aiyé àtijọ́ ọkùnrin kan wà tí orúkọ rè ń jẹ́ Robin Hood. Arúfin ni ọkùnrin náà jẹ́ a sì máa ja àwọn olówó l'ólè. Ṣùngbọ́n gbogbo oun tí ó ń jí ni ó ń kó fún àwọn òtòṣì àti aláìní. Nítorínáà ni gbogbo olówó ìlú bá ìjọba gbìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n ń lé ọkùnrin náà ká ṣùgbọ́n ọwọ́ ò tẹ̀ẹ́ láilái. Nítotrí ore tí ó ṣe fún aláìní gbogbo ni wọ́n ṣẹ f'ara mọ́n ọn tí wọ́n sì tìí lẹ́hìn gbaingbain. Robin Hood jẹ́ alágbára ọkùnrin ó sì mọ ọ̀fà títa ju enikẹ́ni lọ ní gbogbo àgbáiyé! Ọdẹ atamátàsé ni ọkùnrin ogun yìí jẹ́ ó sì tún kó àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́-timọ́ mọ́ra tí àwọn náà mọ ìjà á jà gidigidi. Inú igbó yìí jẹ́ ọ̀kan nínú ibùgbé Robin Hood àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀nyí.  Wọ́n sì mọ gbogbo kọ̀ọ̀rọ̀ inú igbó náà pátápátá. Èyí kún nǹkan tí ọwọ́ àwọn agbófinró ọ̀ fi lè tẹ̀ wọ́n rárá tí wọ́n sì fi jẹ́ àwáàrí fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ mú wọ̀n dè. 
Tí ènìà bá tún tẹ̀ síwájú diẹ̀ sí i, á gun òkè kékeré kan á sì jáde nínú igbó náà. Jíjáde tí ènìà jáde yìí, á bọ́ sí oko nlá kan tí wọ́n fi odi òkúta yípo bí i ti àwọn oko abúlé Youlegrave tí ìrìnàjò ti bẹ̀rẹ̀. Fífò ni odi náà tí ènìà máa fi bọ́ sí inú oko nlá náà. Oko àgùntan ni oko náà ń ṣe.  Ótó bí ọgọ́rùún un wọ́n níbẹ̀ tí ènìà ní láti rìn kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.  Ńṣe ni wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́ tí wọ́n ń jẹ koríko lọ.  Lẹ́ẹ̀kọ̀kan wọ́n á gbójú sókè wòyàn ṣùgbọ́n tí ènìà kò bá ti dẹ́rù bà wọ́n, wọ́n á padà sí koríko jíjẹ. Ẹranko oníwà pẹ̀lẹ́ gbáà ni àgùntàn ń ṣe. Ìṣesí i wọ́n múni rántí ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì tó wípé "Ẹ̀mi ni olùṣọ́ àgùntàn rẹ, ìwọ kì yíò ṣe aláìní".  Òkondoro ọ̀rọ̀ gidi ni eléyìí jẹ́ tí ènìà bá ṣe àgbéyẹ̀wò ìgbésí aiyé àwọn àgùntàn wọ̀nyìí! 
Nkan tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu ní pé gbogbo oko tí ènìà ń kọjá ni kò ní pàdé àgbẹ̀ àbí onílẹ̀ kakan rárá.  Àfi àwọn ẹranko nìkan. Ńṣe ni wọ́n fi àwọn ẹranko wọ̀nyí sílẹ̀ kí wọ́n máa báíyé wọn lọ.
Gbogbo ìrìn tí ènìà ti rìn nígbà tí ó bá kọjá oko àgùntàn yìí tán á ti máa fẹ́ tó bíi wákàtí mẹ́ta sí mẹ́ta-àbọ̀.  Ebi á sì ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní pá ènìà tí kò bá gbé oúnjẹ dání.  Òǹgbẹ á sì ti máa gbẹni pẹ̀lú. Ó dàbí pé àwọn oníṣòwò oúnjẹ agbègbè yìí ti ṣe ìwádìí ibi ti ebi tàbí òǹgbẹ á ti bẹ̀rẹ̀ sí ní máa dàmú àwọn arìnrìnàjò.  Nítorípé bí ènìà bá ṣe jáde kúrò nínú oko àgùntàn ni á ṣe kòóngẹ́ atọ́ka tí wọ́n ṣe síbẹ̀.  Atọ́ka yìí júwèé ilé kan lókèrè tí ìtura oúnjẹ àti nǹkan mímu onírúirú wà fún ríràjẹ. Ìyá arúgbó kan ni ó ń tọ́jú ilé ìtura yìí. Òun náà sì ni ó ń ta oúnjẹ àti nǹkan mímu níbẹ̀.  Arúgbó náà fẹ́ràn láti máà bá àwọn oníbàárà rẹ̀ rojọ́ púpọ̀ nítorípé òun nìkan ni ó wà ni ilé yìí tí ó dádúró tí ó sì jìnà sí abúlé adúgbò ibẹ̀. 
Àgbàlagbà obìrin yìí kìí rí ẹlòmíràn bá sọ̀rọ̀ nítorípé ọkọ rẹ̀ ti ṣaláìsí. Arúgbó náà jẹ́ ènìà rere, àánú rẹ̀ a sì máa ṣe gbogbo arìnrìnàjò. Wọ́n a sì máà yọ̀ mọ́n ọn tí wọ́n á máa báa rojọ́ dáadáa. Ìyá yìí mọ ọ̀nà tí ènìà lè gbà dé ibi àpáta Robin Hood ní kíákíá, ó sì júwèé rẹ̀ fúni tí ènìà bá wí fún-un pé ibẹ̀ ni òun ń lọ.
Ọ̀nà tí arúgbó náà júwèé tọ orí òkè kékeré kan lọ. Koríko hù sí orí òkè náà ṣùngbọ́n ó dàbí ẹnipé ẹnìkan ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀ nítorípé koríko ọ̀hún kò hù kọjá ààlà. Ní ìgbà òtútù nìkan ni yìnyín máa ń ṣábàá rọ̀ . Ṣùgbọ́n lórí òkè àbí àpáta tí ó bá ga sókè tó, yìnyín a máa rọ̀ nígbàkígbà tí ó bá tutù tó nítorípé òtútù mú lókè àpáta ju pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ. Nítorínáà ènìà máa ń ṣábàá bá yìnyín tí ó rọ̀ sórí i koríko orí òkè wọ̀nyìi. Nígbàmíràn àwọn ọmọdé á máa ṣeré lórí i yìnyín náà.  Ènìà tún lè rí àwọn ère tí wọ́n fi yìnyín yìí gbẹ́ síbẹ̀.  Tọmọdé tàgbà ni wọ́n fẹ́ràn láti máa fi yìnyín gbẹ́ ère.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ère ọ̀hún ni wọ́n ti máa bẹ̀rẹ̀ sí yòòrò nígbàtí ènìà bá rí wọn nítorípé yìnyín ò kí ń pẹ́ yòòrò tí òtútù bá káwọ́ ńlẹ̀ díẹ̀ tàbí tí òrùn bá ràn sí i.  Tí ènìà bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, á bọ́ sí ojú òpópónà tí àwọn àgbẹ̀ ń lò fi kó ẹrù àti irinṣẹ́ wọn pẹ̀lú ọkọ̀ akẹ́rù.  Tí yìnyín bá rọ̀ sí ojú ọ̀nà yìí wọ́n á fi ọkọ̀ tí wọ́n fi ń kó ilẹ̀dú kó yìnyín ojú ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ kan, kí ó má fi dí ọkọ̀ wọn lọ́ nà.
Ọ̀nà yìí já sí ojú u títì tí ènìà bá tọ̀ọ́ já tán. Títì yìí ni àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ọkọ̀ akérò ń gbà láti ìlú dé ìlú. Ní àbáwọ títì yìí atọ́ka míràn wà tí ó tún júwèé ilé oúnjẹ arúgbo ẹ̀ẹ̀kan.  Abájọ tí ìyà arúgbó náà ṣe mọ ọ̀nà yìí dáadáa.  Ènìà láti rìn lójú u títì yìí nítorípé kò sí ọ̀nà àfẹsẹ̀rìn kankan lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì yìí bí a ṣe lè ríi lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òpópó ńlá-ńlá míràn. Nítorí èyí, ènìà ní láti fetí sílẹ̀ gidi-gidi kí ó máa ṣọ́ra bí ó ṣe ń rìn lọ kí ó lè yàgò lọ́nà tí ọkọ̀ bá ń bọ̀.  Ewu ń bẹ fún onírìnsè lójú ọ̀nà yìí nítorípé àwọn awakọ̀ míràn a máa wa àwàsaré. Ènìà ní láti ṣọ́ra kí ọkọ̀ má lọ gbá olúwarẹ̀. Ọkọ̀ tí ó ń bọ̀ láti iwájú ṣeérí láti òkèrè nítorípé ọ̀nà tààrà ni títì yìí ńṣe.
Ní apá ọ̀tún ọ̀nà nlá yìí ni ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti ń fọ́ òkúta ńlá-nlá lára apáta. Òkúta yìí ni wọ́n fi ń kọ́lé, tí wọ́n sì fi ń mọn gbogbo àwọn odi tí wọ́n fi yí ilẹ̀ ẹ wọ́n po. Kódà ibẹ̀ ni wọ́n ti ń fọ́ gbogbo òkúta ti wọ́n ń lò ní ìpínlẹ̀ Derbyshire káàkiri.  Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta níbẹ̀.  Gbogbo ibẹ̀ sì ti di kòtò nlá gidi gaan ni.  Kòtò ọ̀hún tóbi tó bíi abúlé kan sí méjì! Kìí ṣe kòtò kékeré rárá. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba nìkan ni wọ́n ní àṣẹ láti wọ ibẹ̀ . Kò sáàyè fún ẹnikẹ́ni míràn.
Ti ènìà bá rin ọ̀nà yìí díẹ̀ , yó máa wo òkúta nlá kan lókèrè.  Nígbànáà ni ènìà yó rí ọ̀nà kékeré tó lọ́ tààrà sí ẹsẹ̀ òkúta nlá yìí. Bí ènìà bá ṣe ń súnmọ́n-ọn lọ ni yó máa pàdé àwọn ènìà míràn tí wọ́n gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dé ibi ọ̀kúta yìí.  Bẹ́ẹ̀náàni òkúta ọ̀hún á máa ṣe bí ẹ̀nipé ó ń paradà.  Á kọ́kọ́ jọ ilé nlá kan. Á tún paradà á dàbí ère kìnìún nlá. Ó dìgbà tí ènìà bá súnmọ́n-ọn tán kí ó tó rí i pẹ́ àwọn òkúta jàǹkàn-jàǹkàn tí wọ́n tò lé arawọn ni.


Òkúta nlá yìí ní ibi méjì tọ́n ga sókè jù ní igun méjéèjì. Alákùrin àtijọ́ Robin Hood ni ìtàn kán sọ fúnwa pé ó fò láti igun sosoro ìkíní sí ìkejì ní ìgbésẹ̀ ẹyọọ̀kan ṣoṣo! Ìdí lèyí tí wọ́n fi ń pe òkúta yìí ní Ìgbésẹ̀ Robin Hood.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìà ni wọ́n máa ń wá sí ibi òkúta yìí láti ìtòsí tàbí ọ̀nà-jíjìn. Àwọn míràn máa ń wá pọ́n òkúta yìí ni, nítorí ó dùn-ún pọ́n gidi-gidi fún wọ́n. Ó di dandan kí olúwarẹ̀ náà gbìyànjú àti pọ́n-ọn dókè.
Ibi a wí la dé yìí o! Gbogbo ìrìnàjò náà gba bíi wákàtí márùún. Tí ènìà bá ṣeré díè tí ó pọ́n òkè tí ó ya àwòrán tán, ó di ilé!

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?