Mojúbà o!Yorùbá bọ̀ ó pòwe. Ó ní "Ẹ jẹ́ ká ṣeé bí wọ́n ti n ṣeé kó lè báà rí bí ó tí n rí". Nítorínáà ẹ jẹ́ kí n fìbà f'óníbà, kí n fọpẹ́ fún ọlọ́pẹ́.
Mojúbà Ọlọ́run Olófin Olódùmarè ọba àkọ́dá aiyé aṣẹ̀dá ọ̀run. Arúgbó ọjọ́ Adàgbàmápààrọ̀oyè Káábíèsí o!
Mojúbà àwọn òbí mi bàbá àti ìyá mi. Ẹkú ìgbìyànjú. Mojúbà gbogbo ẹbí lọ́kùnrin lóbìnrin lọ́mọdé lágbà. Mojúbà gbogbo ọ̀rẹ́ pèlú.
Mojúbà gbogbo aṣájú ọ̀mọ̀wé, ọ̀jọ̀gbọ́n, amòye àti olùkọ́ èdè Yorùbá pátápátá.
Ẹ jẹ́ kó yẹ mí o ìbà ni mo ṣe.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá

Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè