Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá


Ó dáa ó dáa! Mo mọ̀n pé ẹ̀rọ ayárabíàṣá lorúkọ tí computer ń jẹ́ ní èdè Yorùbá. N kò jiyàn rẹ̀ rárá o. Dájúdájú gbogbo wa la ti gbà pé orúkọ rẹ̀ nìyen. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá fojú inú wòó, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe ní alẹ́ ọjọ́ kan, ẹ ó ríi pé orúkọ yìí kù díẹ̀ káà tó!

Ní alẹ́ ọjọ́ tí mo ń sọ yìí, mo tan ẹ̀rọ ayárabíàṣá mi pé kí n sáré ṣiṣẹ́ kan kíakiá kí n tó lọ sùn. Títàn tí mo tàn án tán, lóbá dí kùùrùrù, ó di kẹẹrẹrẹ. Bí ó ti ń sún kẹrẹ ni ó ń fà kẹrẹ. Nǹkan tí kò gbà ju ìsẹ́jú kan lọ tẹ́lẹ̀, ó di oun tí a ń fi ìsẹ́jú mẹ́rin ṣe. Gbogbo ẹ̀ wá ń fẹsẹ̀ falẹ̀ bí ìjàpá. Ẹ̀rọ wá di ẹ̀rọ àfìdíwọ́bíìgbín!

Àb’ẹ́ẹ̀ríǹkan? ǹjẹ́ orúkọ yìí péye mọ́n? Ótì o, èmi ò rò bẹ́ẹ̀ rárá. Nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nipé lẹ́hìn bíi ọdún méjì láti ìgbà tí ènìà bá kọ́kọ́ ra ẹ̀rọ ní títun, ẹ̀rọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́. Àwọn nǹkan inú ẹ̀rọ tí wọ́n ń mú u ṣiṣẹ́ náà a máa gbó pẹ̀lú. Àmọ́ pàápàá jùlọ, nǹkan tó fàá nipé bí àsìkò àti ìgbà ṣe ń lọ síwájú ni iṣẹ́ tí a ń fún ẹ̀rọ yìí ṣe ń ṣòro síi tí ó sì ń wúwo síi. Agbára ẹ̀rọ á sì máà dínkù síi titi agbára rẹ̀ ò fi ní ká iṣẹ́ tí a ń fi ṣe dáadáa mọ́n. A jẹ́ pé fún bíi ọdún kan péré náà ni ẹ̀rọ yìí fi ń yára bí àṣá o.

Ọrúkọ wo láà bá wá sọ Computer ní Yorùbá? Óyá ẹ jẹ́ ká gbé e yẹ̀wò. T’ọ̀wọ̀ t’ọ̀wọ̀ ni mo fi sọ̀rọ̀ yí o, ṣùgbọ́n èro mi ni pé àwọn tí wọ́n sọ computer ní ayárabíàṣá, ìtumọ̀ "Computer" àti iṣẹ́ tí ó ń ṣe kò yé wọn dáadáa ni.

Láti èdè Latin ni "Computer" ti jáde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀. "Computare" ni ọ̀rọ̀ yí gan-gan ó sì túmọ si "kíkà" tàbí "sísírò" ní Yorùbá. Ní nǹkan bíi 1940 sí 1945 ni wọ́n ṣẹ̀dá Computer àkọ́kọ́ ní ìlẹ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Iṣẹ́ tí ó kọ́kọ́ ń ṣe nígbà náà ni ìsirò. Àwọn ìsirò ònkà nlá-nlá tí ó sòro púpọ̀ púpọ̀ fún ọmọ ènìà láti ṣe ni ẹ̀rọ yìí nṣe ní kíákíá láì tàsé.

Ìgbà tí ìlọsíwájú dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ọ̀nà fi ẹ̀rọ yìí ṣe onírúirú iṣẹ́ míràn bíi ìwé kíkọ, kíkà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. L’áyé òde òní, ìmọ̀-ẹ̀rọ yìí ti gbòòrò gidigidi, ó sì ti dàgbà sókè dé ibi pé kò fẹ́ẹ másìí nǹkan ẹ̀rọ ìgbàlódé kankan tí kò ní ẹ̀rọ yìí nínú. Àti pé kò fẹ́ẹ másìí iṣẹ́ tí kò lè ṣe. Ó ń ṣiṣẹ́ amóhùmáwòrán, ó ń ṣiṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsì. Kódà ayé tó d’ayé ayélujára yìí, ó tún ń ṣiṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.

Kí laà bá wá pe Computer yìí ní Yorùbá tí kò bá tọ̀nà, tí kò bá bá ìtunmọ̀ mu rẹ́gí-rẹ́gí? Ẹ̀rọ Aṣèsirò ni o!

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè