Bàtà Àràmàndà
Abẹsẹ̀ gígùn mà wá dáràn o! Ẹ ní kílódé? Yó dáa fún yín!

Ṣèbí tí èyàn bá ń wá ìbọ̀sẹ̀ tàbí sòkòtò rà, èyí tó bá gùn délẹ̀ tàbí èyí to wọ̀’yàn lẹ́sẹ̀ l’èyàn ń wá? Àyàfi tí irúfẹ́ oge kan bá gbòde tójẹ́pé ṣòkòtò-ò-balẹ̀ l’olúwarẹ̀ ń kúkú wá ká. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣòkòtò ó gbọdọ̀ gùn délẹ̀ ni. Ó sì yẹ kí ààyè ó gba esè nínú u bàtà pẹ̀lú.

Ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọnsẹ̀ àwọ́n géndé, láìí ṣe t’ọmọdé, máa ń ṣábàá bẹ̀rẹ̀ láti 7 dé 12, ìyen fún génde ọkùnrin. Ìgbàmíràn èyàn tún lè rí 6 fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ kékeré, tàbí 13 (tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ) fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ gòdògbà. Tí géndé ọkùnrin mẹ́wàá bá wọn ẹsẹ̀, mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án nínu wọn ni wọ́n á bọ́sí láti 7 dé 10. Nítorí èyí ni àwọn onísọ̀ ibọ̀sẹ̀ dín iye bàtà tó ju 10 lọ kù. Báyìí, wọ́n a le rí bàtà tà dáadáa síi, nítorípé díẹ̀ náà ni iye àwọn oníbàárà wọ́n tí ẹsẹ̀ ẹ wọ́n ju 10 lọ.

Nǹkan tó fa wàhálà fún ẹlẹ́sẹ̀ ńlá rèé o! Olúwa rẹ̀ ó wá pàráàró títí yó fi sú u. Tí ẹni ọ̀hún tún bá ṣoríire tó rí ibọ̀sẹ̀ tó bẹ́sẹ̀ ẹ rẹ̀ mu, bàtà ńlá yìí ó tún ṣe aláwọ̀ ọ kàlákìnní bákan. Yó wá rí ṣàbìlà-sabila gbúgun-gbùngun bíẹnipé wọn kò f’ẹ̀lẹ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ bí àwọn ìyókù. Gbogbo rẹ̀ ò wá ní bójúmu rárá. Bẹ́ẹ̀náàni fún ṣòkòtò.

Àb’ẹ́ẹ̀rí nǹkan? Kí ni ẹní bá ga tó sì ní ẹsẹ̀ ńlá ó wa ṣe?

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá

Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè