Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè


Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kaàrún ọdú un 1953 ni Elizabeth gorí oyè. Ó wa jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba orílẹ̀èdè UK àti gbogbo àwọn ilú káàkiri àgbáyé tí wọ́n wà lábẹ́ UK nítorí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ló mú wọn sìn.

Orílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣùgbọ́n òmìnira dé fún wa ní ọdún un 1960, a sì kúrò lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ní ọjọ́ àyájọ́ ọdúnìí tó pé ọgọ́ta ọdún tí Elizabth gorí oyè, àkànṣe ńlá gidi ló jẹ́. Ọjọ́ márùn-ún gbáko ni wọ́n fi ṣe ètò ẹ̀yẹ yìí. Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì dá ọjọ́ Ìṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsimin fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n ó le r’áàyè lọ wòran níbi ayẹyẹ nlá yìí. Ṣé ọjọ́ Ajé kúkú ti jẹ́ ọjọ́ odún kan tẹ́lẹ̀, gbogbo ẹ̀ wá jẹ́ ọjọ́ mẹ́rin – Àbámẹ́ta, Aìkú, Ajé àti Iṣẹ́gun – tí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyàn r’áàyè jáde wòran dáadáa. Kódà ọ̀pọ̀ ló wá láti ọnà jíjìn àti ìdálẹ̀ láti darapọ̀ mọ́n èrò tó wá bọ̀wọ̀ fú ọba yìí.

Onírúirú àrà ní wọ́n dá o! Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọpọ́n àti ọkọ̀-ojú-omi ni wọ́n dárà lórí odò Thames fún ọjọ́ méjì. Elizabeth fúnrarẹ̀ wà nínú ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀-ojú-omi yìí. Bíótilẹ̀jẹ́pé òjò ń rọ̀, kò dí ayẹyẹ náà lọ́wọ́ rárá. Ní ọjọ́ kẹẹ̀rin ètò yìí, ìyẹn ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Elizabeth ati Àrẹ̀mọ rẹ̀ Charles àti aya rẹ̀, àti àwọn ọmọ àrẹ̀mọ William àti Harry pẹ̀lú ìyàwó William, wọ́n yọjú sí èrò ńlá tí wọ́n péjọ sí iwájú àfin rẹ̀. Èyí mú kí wọ́n pariwo kí wọ́n sì pàtẹ́wọ́ kárakára, tí inú u gbogbo wọ́n ńdùn gigi nítorípé wọ́n nífẹ̀ ẹ ọba-bìnrin yìí púpọ̀. Kíákíá wọ́n bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ tí wọ́n máa ń kọ fún ọba ní ilẹ̀ náà. Orin náà túmọ̀ pé kí Ọlọ́run dá ọba wọ́n sí o! Bí wọ́n ti ń kọ orin yìí tán ni oríṣìíríṣìí ọkọ̀-òfurufú fò kọ̀já lókè e àfin náà. Ọkọ̀-ofurufú ti wọ́n fi ń jagun ní wọ́n jẹ́. Ọ̀wọ̀ ńlá sì ni wọ́n fi bù fún Elizabeth nítoripé ti àtijọ́ ni wọ́n, àwọn èyí tí wọ́n fi jagun ńla kan nígbàtí ọba-bìnrin yìí kọ́kọ́ gorí oyè. Èyí tún mú kí gbogbo èrò kígbe kí wọ́n sì pàtẹ́wọ́. Lẹ́hìn èyí ni Elizabeth àti àwọn ẹbí i rẹ̀ padà wọnú àfin lọ.

Fún wákàtí mélòó kan lẹ́hìn tí Elizabeth wọlé lọ tán, àwọn akọrin tí wọ́n lókìkí tí wọ́n sì gbajúmọ̀ gorí ìtàgé ńlá tí wọ́n kọ́ síwájú àfìn ọba, wọ́n sì ń fi orin aládùn dá àwọn erò tó péjọ l’árayá.

Elizabeth ọba ilẹ̀ Gẹ̀ésì. Ki adé pẹ́ lórí o. Kí bàtà pẹ́ lẹ́sẹ̀ o!

[Alákọ̀wé kọ àkọsílẹ̀ yìí ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹhìn]

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá