Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn



Ṣé mo sọ níjọ́sí pé ìfẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bímọ. Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà ọmọ tí wọ́n bí ju ẹyọ kan ṣoṣo lo. Àwọn ọmọ náà ni Ààrùn, Àìsàn, Àìlera àti Àárẹ̀.

Àwọn ọmọ wọ̀nyí a máa farahàn ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrà, wọn a sì máa da ọmọ-ènìyàn l'áàmú. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà àrà náà nìwọ̀nyí;

Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìfúnpá Gíga, Ìtọ̀ Ṣúgà, Wárápá, Àìsàn Ọkàn, Ọpọlọ Wíwú, Ojú Fífọ́, Ìdákọ́lẹ, Àpọ̀jù Ọ̀rá-Ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Abí ẹ kò rí i pé àjẹjù ṣúgà kò dára fún ọmọ ènìyàn rárá bí? Ó yẹ ká yẹra fún un nígbà gbogbo, kí ó má baà ṣe àkóbá fún wa.

Toò, ẹ jẹ́ ká fi man báhun lónìí nítorí pé "ṣókí l'ọbẹ̀ oge". Èmi ni Alákọ̀wé yín ọ̀wọ́n. Ó tún dìgbà kan ná.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?