Ẹkú ọjọ́dọ́gba àná o

Yoòbá ní "Aiyé nyí lọ biri-biri bí òkúta". Àṣé ìtunmọ̀ nbẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí ju bí a ṣe rò lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀jìnlẹ̀ ti fi yé wa pé ọ̀bìrìkìtì ni ilé-aiyé nṣe, kìí ṣe pẹlẹbẹ. Bí ilé-aiyé ṣe tóbi tó, àti bí àwa ọmọ ènìà ṣe kéré síi to, ló fi dà bẹ́ẹ̀ lójú tiwa.

Àti pé ilé-aiyé yìí ò dúró lójú kan rárá. Nṣe ló nyí birir bí òkòtó. Ó sì tún npòòyì yí òòrùn po. Ìyíbiri ẹyo kan ló nfúnwa ni ẹyọ ọjọ́ kan. Nítorí pé ihà ilé-aiyé kan ló kojú sóòrùn lẹ́ẹ̀kannáà, tí ìdàkejì á sì kọjú sí òkùnkùn òfurufú, ìmọ́lẹ̀ òòrùn yìí ni a npè ní ojúmọ, tí òkùnkùn ṣì njẹ́ àsìkò alẹ́ àti òru. Wákàtí mẹ́rìnlélógún ni ilé-aiyé fi nyí biri lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, èyí tí nṣe ọjọ́ kan.

Nítorí ilé-aiyé dàbí ọ̀bìrìkì, o yẹ́ kí iye wákàtí tí ihà a rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fi kọjú sóòrùn jẹ́ méjìlá, kó sì kọ́ju sókùnkùn fú iye wákàtí kannáà. 12 + 12 = 24. Ìyẹn ni pé kí ojúmọ́ àti ilẹ̀ṣú jẹ́ dọ́gba-dọ́gba. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní ihà àríwá ilé-aiyé àti ihà gùsù aiyé pẹ̀lú, ọjọ́ ò dọ́gba rara.
 


Ìdí èyí ni pé ilé-aiyé rọra fì sí egbẹ́ kan. A jẹ́ pé bí ó ṣe nyí òòrùn po, nígbà míràn á kọ́ orí (àríwá) sóòrùn, nígbàmíì á kọ ìdí (gusu) síi. Ìgbà tí ilé-aiyé kórí sí òòrùn yìí ni a máa nrí ìgbà ooru. Ìgbà tó kọ̀dí sí òòrùn ni ìgbà òtútù ní ìhà àríwá ilé-aiyé. Ààrin ìgbà méjéèjì wọ̀nyí ni ìgbà ìrúwé tí ìgbà òtútù nparadà di ìgbà ooru, àti ìgbà ìwọ́wé tí ìgbà ooru nparadà di ìgbà òtútù. nkan bíì ọsù mẹ́ta-mẹ́ta ni ìgbà kọ̀ọ̀kan ngbà, tí ìgbà mẹ́rẹ̀rin bá kọjá tán ni ó di ọdún kan, tí nṣe oṣù méjìlá. 3 x 4 = 12.
(Gbogbo nkan to bá nṣẹlẹ̀ ní àríwá ilé-aiyé, ìdàkejì rẹ̀ ló ma nṣẹlẹ̀ ní gusu. Kí ng fi gé àkọsílẹ̀ yìí kúrú, ti àríwá nìkan ni mo mẹ́nu bà.)

Ìyẹn ló fàá tó fi jẹ́ pé nígbà ooru, ọjúmọ́ máa ngùn ju ilẹ̀ṣú lọ. Òòrùn á tètè là nídàájí, á sì pẹ́ wọ̀. Ìdàkejì rẹ̀ sì làá rí nígbà ọ̀gìnìntìn tí nṣe ìgbà òtútù. Bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe nlọ ni ojúmọ àti ilẹ̀ṣú a máa gba ìsẹ́jù méjì-méjì lọ́wọ́ arawọn, títí tí wọ́n a fi dọ́gba ní wákàtí 12 sí 12. Ẹ̀ẹ̀mejì péré ni ọjọ́ ndọ́ga báyìí lọ́dún. Ọ̀kan bọ́sí ìgbà ìrúwé tí ojúmọ́ ngùn síi. Ìkejì bọ́sí ìgbà ìwọ́wé tí ojúmọ́ nkuru síi. Ní ọjọ́ méjéèjì wọ̀nyí ni ilé-aiyé kọ ẹ̀gbẹ́ sí òòrùn. Tí àríwá àti gùsù aiyé kọ ara sóòrùn ní dọ́gba-dọ́gba, tí wakàtí ìmọ́lẹ̀ òòrùn àti òkùnkùn ṣì jẹ́ méjìlá gérégé.

Àwọn ọjọ́ ọṣù tí ọjọ́ ndọ́gba báyìí a máa fi ọjọ́ kan sí méjì yàtọ̀ lọ́dọọdún. Lọ́dúnnìí, ọjọ́dọ́gba ìgbà irúwé bọ́sí 20 Ẹrẹ́nà (oṣù kẹta). Wọ́n fi yé wa pé ó yára dé lọ́dúnìí. Pé láti ọdún 1896 ló ti tètè dé báyìí gbẹ̀hìn. Ọjọ́dọ́gba ìgbà ìwọ́wé bọ́sí 21 Ọ̀wẹ́wẹ́ (ọsù kẹsàn-án), tí nṣe àná!

Nítorí pé ilẹ̀ Yorùbá súnmọ́ ààrin ọ̀bìrìkìtì aiyé, ènìà ò lè rí iyàtọ̀ púpọ̀ láàrin ojúmọ́ àti ilẹ̀ṣú rárá, Bíótilẹ̀jẹ́pé ìyàtọ̀ isẹ́jú mélòókan máa nwà. Àmọ́ fún àwọn tó ngbé ní ìhà aríwá tàbí gùsù àgbálá-aiyé, ìyàtọ̀ hàn gedegbe. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wa ní ilẹ̀ Yorùbá, a máa nkírawa gẹ́gẹ́ bí ojú ọjọ́ ti rí ni. A jẹ́ pé mo kí gbogbo yín ẹkú ọjọ́dọ́gba àná o!

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!