Pàtàkì Ìwé Kíkọ Àti Kíkà Ní Èdè Abínibí


Oun tí a ní là ń náání. Àwọn àgbà Yorùbá ni wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ ní òde òni àwa ọmọ Odùduwà ń náání oun tiwa bí? Ọ̀rọ̀ ọ́ pọ̀ níbẹ̀ o ẹ̀yin ará mi. Ó dáa ẹ jẹ́ ká mú'kan níbẹ̀ ká gbé e yẹ̀wò.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ràn láti máa sọ èdè Yorùbá lẹ́nu mọ́n, dájú-dájú púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí gbọ́ ọ l'ágbọ̀ọ́yé, wọn kò kàn kí ń sọ ọ́ ni.

Lára àwọn agbọ́másọ wọ̀nyí, bóyá la lè rí ìkankan nínú wọn tó mọn èdè Yorùbá kà dáradára, ká tilẹ̀ má sọ̀rọ̀ ọ kíkọ. Àgàgà tí a bá fi àmì sọ́rọ̀, a máa fa ìrújú fún púpọ̀ nínú wọn. Ó mú mi rántí nkan tí ẹnìkan wí lóri Twitter níjọ́sí. Ó ní Yorùbá kíkọ̀ èmi Alákọ̀wé fẹ́ jọ èdè Lárúbáwá lójú òun nítorí àwọn àmì ọ̀rọ̀ tí mo máa ń fi sí i. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún pa mí ní ẹ̀rin lọ́jọ́ náà kì í ṣe díẹ̀.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ burúkú òhun ẹ̀rín kọ́ rèé ni ẹ̀yin èèyàn mi? À á ti wá gbọ́? Ṣé ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípà èdè Gẹ̀ẹ́sì kíkọ? Ótì o! Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àbí ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Faransé ti ń ránmú sọ Faransé bí? Èmi ò rí i rí o.


Kí ló wá fà á? Ìkíní ni pé l'óòótọ́ a kò ní ètò ìkọ̀wésílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá kí àwọn Lárúbáwá àti àwọn ará Úróòpù tó dé. Ajẹ́pé kò sí nínú àṣà wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àtẹnudẹ́nu àtìrandéran ni àwá ń ṣe ní àtètèkọ́ṣe. Ṣùgbọ́n ayé àtijọ́ nìyẹn o. Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́ ni. Èdè Yorùbá ti di kíkọsílẹ̀ ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣíwájú èdè káàkiri Afirika nípa kíkọsílẹ̀.

Ìkejì ni pé àwa ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Káàárọ̀oòjíire ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pátápátá. Kódà, àfi bí ẹni pé ẹlòmíràn kórira èdè abínibí tirẹ̀ gan-an ni. Nítorí ìdí èyí a kì í ṣe àmúlò èdè Yorùbá fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ile-ìwé wa, tàbí fún ìjírórò l'áwùjọ òṣèlú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Yorùbá ń parun lọ kọ́ yìí? Àbí kí ni ọ̀nà àbáyọ? Àwọ̀n àgbà Gẹ̀ẹ́sì bọ̀ wọ́n ní "Ìrìnàjò ńlá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo". Gẹ̀ẹ́sì káàbọ̀ o jàre. Ọgbọ́n àgbà ń bẹ lọ́dọ̀ tiwọn náà. Ajẹ́pé Yoòbá gbọ́n Èèbó gbọ́n ni wọ́n fi dá ilẹ̀ London :)

Ká tiẹ̀ pa àwàdà tì. Kíni irúfẹ́ ìgbésẹ̀ kíní tó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ńlá ìsọ́jí èdè Yorùbá kíkọ àti kíkà? Toò, ìyẹn dọwọ́ olúkúlùkù wa. Láyé òde òní gbogbo wa ni ònkọ̀wé níwọ̀n ara tiwa. Yálà lórí ẹ̀rọ ojútáyé nì tí a mọ̀n sí Facebook, tàbí àwùjọ ẹjọ́wẹ́wẹ́ nì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Twitter. Kíní ṣe tí àwa ò máa ṣe àmúlò èdè wa lórí àwọn àwùjọ wọ̀nyí déédé. Lóòótọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló pabambarì káàkiri àgbàyé, àmọ́ a láti gbé èdè tiwa náà lárugẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ibòmíràn ṣe máa ń ṣe.

Toò, ọ̀rọ̀ mi ò jù báyìí lọ. Ṣé wọ́n ní "ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá" Tó tó ṣe bí òwe. Ìpàdé wa bí oyin o.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá