Ènìyàn àti Ṣúgà


Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé "a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́". Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé.

Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe.

Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá.

Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo - ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá àyè wa. A ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ tó ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àgbáyé yìí ò tẹ́ wa lọ́rùn o. A ní dandan àfi ká ṣe tí inú wa. A ní iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ò dára tó, àfi ká tún un ṣe ní ìlànà tiwa. Àpẹrẹ ìwà yìí kan rèé;

Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn kọ̀ ó ní oyin ò dùn tó o. Ó tún wípe rárá, ìrèké náà kù díẹ̀ káàtó. A ní àfí ká ṣe ìwádìí nkan tó fa adùn inú àwọn nkan wọ̀nyí, kí a lè ṣe wọ́n ní ìlànà tiwa.

Ọmọ ènìyàn bá fún omi inú ìrèké, ó gbé e raná ti omi náa fi gbẹ, tí ó fi ku kiní kan funfun báláhú. Kiní ọ̀hún jọ iyọ̀, àmọ́ dídùn rẹ̀ yàtọ̀ sí ti iyọ̀, ó jọ ti oyin àti ìrèké. Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ní "Kò tán bí!? A ti rí ìdí abájọ, ojú ti ẹ̀yin ọmọ kòkòrò!".


Ọmọ ènìyàn wo kiní ọ̀hún títí ó ní "Ṣúgà la ó máa pè ọ́"

Ṣúgà amáyé dùn
Ìwọ ni gan-an ajẹmáleètu
Àdídù inú oyin abara funfun
Àní ìwọ gan-an lọ dùn jù
Ìwọ ni ìrèké gbóríyìn fún
Àwọ̀ àlà rẹ ń wọ̀ mí lójú


Láti ìgbà yìí ni ọmọ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ń tọ́ kiní funfun ọ̀hún sí gbogbo nkan jíjẹ àti mímu. Wọn a máa tọ́ ṣúgà sí omi. Wọn a máa tọ́ ọ sí ẹ̀kọ mímu. Kódà àwọn kan a máa lá a ní gbẹrẹfu.

Àwọn àgbàlagbà Yorùbá ti parí ọ̀rọ̀ tipẹ́-tipẹ́. Wọ́n ní "Àṣejù ni bábá àṣetẹ́". Ọ̀rọ̀ àgbà rèé, kì báà pẹ́, a máa padà ṣẹ nígbẹ̀yìn ni. Nígbà tó yá, ifẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bá bímọ. Ìfẹ́ ọ̀hún ni àṣejù. Ọmọ náà ni àṣetẹ́.

Kí wá ló ṣẹlẹ̀? N ó fi tó o yín létí láìpẹ́. Ẹ padà wá gbọ́ àbọ̀ ọ̀rọ̀.

Ẹ ṣeun, mò ń bọ̀ ná.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?