Yorùbá101
Yorùbá rẹwà l'édè. Ó dùn-ún sọ l'ẹ́nu, ó sì dùn-ún gbọ́ l'étí. Nínú ọrin kíkọ, ewì kíké tàbí òwe pípa, èdè Yorùbá ò l'ẹ́gbẹ́ ńbìkankan. Èdè tó kún fún àṣà tó wuyì tó sì jọjú ni Yorùbá ń ṣe. Ìdí ẹ̀ rèé tó fi ṣeni láàánú nígbàtí àwọn onímọ̀ fi yé wa pé tí a kò bá ṣọ́ra, èdè ńlá yìí á di nkan ìgbàgbé láàrin ọgọ́rùn-ún ọdún. Á wá di nkan ìtàn tí a ń tọ́ka sí láti òkèrè pé àwọn kan sọ èdè náà l'áyé àtijọ́.
Oríṣìíríṣìí ìdí ló fà á tí èdè Yorùbá ṣe ń jíjó àjórẹ̀hìn báyìí. N kò ní mẹ́nu ba gbogbo wọn, àmọ́ ọ̀kan ni pé àwọn ọmọ tí à ń bí l'óde òní ò kí ń ṣábàá gbọ́ Yorùbá mọ́. Yálà nítorí pé a bí wọn sí ìdálẹ̀ níbi tí wọn kò ti ń sọ Yoòbá ni, tàbí àwọn òbí ọmọ kò fi kọ́ wọn.
Ìdíkídìí tí kì báà jẹ́, àwọn ojúlówó ọmọ Yóòbá kọ̀ọ̀kan ti dìde káàkiri ilẹ̀ wa, àti káàkiri àgbáyé láti rí i pé èdè yìí kò parun, kò sì di nkan ìgbàgbé. Wọn ń ṣe akitiyan ní ọlọ́kanòjọ̀kan ní ọ̀ná tí wọ́n ní agbára láti ṣe àlátìlẹ́hìn fún èdè ilẹ̀ baba wọn.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Oòduà wọ̀nyí ni ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Olùkọ́ Àṣà. Àwọn ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá lórí iPad, Android ati ẹ̀rọ Ayárabíàṣá. "Yoruba101" ni wọ́n pè é, ó sì wà fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, papàá fún àwọn ọmọdé. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú àwòrán lókè, Yorùbá pọ́mbélé ni olùkọ́ yìí jẹ́. Ó dé fìlà abetíajá sórí, ó wọ ìlẹ̀kẹ̀ iyùn sọ́rùn. Bíótilẹ̀jẹ́pé ẹlẹ́rìn-ín ẹ̀yẹ ni ọ̀gá-tíṣà yìí jẹ́, kò gba àrífín láàyè rárá o! Ẹgba ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ fún aláìgbọràn ọmọ gbogbo, gẹ́gẹ́ bí àṣà wa ní'lẹ̀ káàárọ̀-oòjíire.
Àwọn ètò ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ míràn náà wà lọ́rí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé wọ̀nyí o, àmọ́ nkan tí Yorùbá101 tún fi yàtọ̀ ni lílo "ìṣiré". Èyí á mú kí àwọn ọmọdé fẹ́ràn láti máa lò ó gan-an, kí wọ́n sì máa rántí ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ wọn dáradára. Nítorí àwọn ọmọdé fẹ́ràn eré ṣíṣe, gbogbo ọkàn àtí ọpọlọ wọ́n ní wọ́n máa ń kọ sí i.
Èrò tèmi ni pé, nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èdè tó yànjú, ètò yìí kù díẹ̀ níbìkọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ó dámi lójú pé Olùkọ́ Àṣà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni. "Ótúnkù" ni ìbọn ń ró, l'áṣà àwọn àgbà. Ẹ jẹ́ ká darapọ̀ mọ́n Olùkọ́ Àṣà, kí a báwọn gbé iṣẹ́ ọpọlọ wọn lárugẹ, kí a gbìmọ̀pọ̀ ṣe alátìlẹ́hìn fún ìlọsíwájú èdè àti àṣà ilẹ̀ wa.
Ẹ tẹ̀lé Olùkọ́ Àṣà lórí Twitter --> @Genii_Games
Fún iPad --> Yorùbá101
Comments
Post a Comment