Igi ńlá ni igi ọ̀pẹ

Ìrìnàjò kan tí mo rìn dé Andalusia ní orílẹ̀èdè Spain níjọ́sí, oríṣìí nǹkan l'ojú rí níbẹ̀.  Mo rí awọn ìlú kan tí ó jẹ́ pé òkúta funfun gbòò ni wọ́n fi kọ́ gbogbo àwọn ilé ibẹ̀.  Mo rí afárá ńlá alájà méfà.  Kódà mo tún rí ibi tí àwọn odidi igi ti ń hù lábẹ́ odò.  Sùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan ìyanu tí mo rí, èyí tó pe àkíyèsí mi jùlọ ni bí igi ọ̀pẹ ṣe pọ̀ níbẹ̀ tó.  Kò sí ibi tí igi ọ̀pẹ ò hù sí káàkiri.  Ní àsìkò tí mo lọ tún wá bọ́ sí ìgbà ìkórè.  Ajẹ́pé àwọn ẹyìn ti pọ́n, tí wọ́n sì rẹ̀ dà sílẹ̀ káàkiri.

Kí ló wá yà mí lẹ́nu?  Ẹ jẹ́ mọ̀n pé ibi àwọn ẹyìn bá rẹ̀ sí, ibẹ̀ náà ni wọ́ ń rà sí o!  Àyàfi tí ẹyẹ tàbí ọ̀kẹ́rẹ́ bá fi jẹ.  Láàrin ìgboro kẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba a máa fi ọkọ̀ akólẹ̀ kó wọn lọ dà sí ààtàn.  Wọn kò ka igi yìí kún nǹkanan níbẹ̀.  Èso igi náà kò jọ wọ́n lójú pẹ̀lú.

Ní ilẹ̀ Oòduà, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe káàkiri àwọn ilẹ̀ adúláwọ̀ gbogbo, pàtàkì ni igi ọ̀pẹ jẹ́.  Ara igi yìí la ti ń rí ẹmu funfun tí ṣe ògùrò tí àwọn àgbà ò jẹ́ fi ṣàwàdà.  Ara rẹ̀ la ti ń rí epo pupa tí í ṣe agbátẹrù iṣu lọ́nàfun. Ara rẹ̀ la ti rí màrìwò tí a fi ń ṣe ọwọ̀ ìgbálẹ̀ at ọjọ̀ ewédú. Èkùrọ́ ńkọ́?  Òun ló ń fún wa ní àdí èkùọ́ àti òrí.  Àwọn kan a tún máa fi màrìwò ṣe òrùlé ilé.  Bẹ́ẹ̀ wọn a máa fi èpo ẹyìn gbígbẹ ko iná ààrò kó lè baà jò dáadáa.  Àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìdí rèé tó fi yà mí lẹ́nu pé igi pàtàkì yìí kò da nǹkankan lóju wọn, tí èso rẹ̀ sì ń ṣòfò dànù bẹ́ẹ̀.  Ǹjẹ́ ẹ jẹ́rìí Alákọ̀wé yín bí?  Gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Oòduà, mo wá ibìkan tó tẹjú pẹrẹsẹ, mo wá òkúta kan, mo ṣa èkùọ́ mélòókan, mo pa wọ́n, mo dà wọ́n sẹ́nu, mo jẹnu wọ̀mù-wọ̀mù, mo gbé e mì kàló.  Gbogbo wọn wá ń wò mí bàùn bí àguntàn Ìbàdàn.  Èmi náà bá ranjú mọ́n wọn padà.  Mo jẹ́ kó yé wọn pé "òkò tí a bá sọ lu ọ̀pẹ ní í sọ padà sí ẹni".  Òwe Yoòbá kan ni.





Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?