Roomba amáíyérọrùn
Ìmọ́tótó borí ààrùn mọ́lẹ̀. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gidi ni.
Láíyé àtijọ́, ṣèbí ọwọ̀ ìgbálẹ̀ tí wọ́n fi màrìwò ọ̀pẹ ṣe la fi ngbálẹ̀. Òun náà la fi ngbọn jànkáríwọ̀ kúro lára ògiri inú ilé. Láíyé àtijọ́ tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí ni wọ́n ngbé pọ̀ nínu agbolé kannáà, àjọ́gbá ni ilẹ̀, àjọṣe ni iṣẹ́. Tí àwọn púpọ̀ bá pé jọ gbálẹ̀, kíá kiá ni wọ́n ngbálẹ̀ tán. Iṣẹ́ náà a wá dàbí ti ikán tọ́n parapọ̀ tọ́n mọ'lé. Àjọṣe ló rọrùn.
Láíyé òde òní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ndá gbé, tàbí kí wọ́n pé ẹyọ méjì péré nínú ilé kan. Pàápàá ní àwọn ìdílé alákọ̀wé. Aiyé daiyé òyìnbó :) Nítorí ìgbésí aiyé alákọ̀wé yàtọ̀ sí ti àtijọ́, àti pé jíjí tí wọ́n njí lọ ibiṣẹ́ lójoojúmọ́ ò fààyè sílẹ̀ fún ilẹ̀ gbígbá. Àmọ́ o, òyìnbó tó saiyé dẹ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ-ìgbálẹ̀ níjọ́sí ti tún gbé tuntun dé o. Roomba ni wọ́n npèé.
Yàtọ̀ sí ẹ̀rọ-ìgbálẹ̀ alátìká, Roomba yìí máa nfúnrarẹ̀ gbálẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ enìkankan ni. Nígbà tí èèyàn bá kọ́kọ́ tàn án, Roomba á fúnni ní ànfàní àti ṣe ẹ̀tò àsìkò tí èèyàn fẹ́ kó gbálẹ̀ lójúmọ́. Èèyàn lè sọ ọjọ́ ọ̀sẹ̀ wo ni kó gbálẹ̀, ati ní wákàtí wo. Tí àsìkò bá tó Roomba
a tají á bẹ̀rẹ̀ sí í gbálẹ̀. Tó bá sì ṣe tán á padà sí ibi tí ó nsùn sí. Ó ní àpọ̀ nínú tó nfa gbogbo ìdọ̀tí sí. Èèyàn ní láti da ìdọ̀tí inú ẹ̀ nù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó bá ti kún.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó nlo Roomba yìí a máa fi àkókò ìgbálẹ̀ sí ìgbà tí wọn ò bá sí n'lé. Nígbà tí wọ́n bá wọlé dé, ilẹ̀ á ti mọ́n tóní-tóní. Roomba náà a ti dákẹ́ rọ́rọ́ sí ẹ̀bá ibi tí wọ́n gbé e sí.
Njẹ́ Alákọ̀wé ò ní wá ọ̀nà ra ọ̀kan báyìí? Àb'bẹ́ẹ̀ ríi pé ìrọ̀rùn gbáà ni? Ó kàn jẹ́ pé ó fẹ́ gbówó lérí díẹ̀.

Comments
Post a Comment