Ilé tó nléfò nínú igbó
Ni ọ̀sẹ̀ tó kọjá, èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi kan rin ìrìnàjò-ìgbafẹ́ lọ sí ìgbèríko kan. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ló wọ́pọ̀ jù ní ìgbèríko náà, ó sì ṣe kìkì igbó àti oko. Onírúirú nkan ọ̀gbìn àti èso ni àwọn àgbẹ̀ náà ngbìn, wọ́n sì nsin oríṣìíríṣìí ẹranko. Màlúù, ẹlẹ́dẹ̀, tòlótòló àti adìẹ n'ọ́n pọ̀jù nínú àwọn ẹranko tí àwọn àgbẹ̀ ìgbèríko náà nsìn.
Òwúrọ̀ kùtù-kùtù kan ni èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi wọ̀nyí gbéra, tí a kórí sí inú igbó kan. Bótilẹ̀jẹ́pé ojú-ọjọ́ ṣe bí ẹní fẹ́ rọ̀'jò, nkan táa lọ ṣe níbẹ̀ náà ni àrìnká káàkiri inú igbó àti pákáko ẹ̀bá ìgbèríko ọ̀hún, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa bí onírìnàjò.
Kò pẹ́ díẹ̀ táa rìn nínú igbó náà dé'bìkan ni mo pe àkíyèsí àwọn ẹlẹgbẹ́ mi sí nkankan tí mo rí lókèrè. Àwọn igi àti ewéko kan díwa lójú díẹ̀ tí a kò sì rí nkan náà dáadáa. A bẹ̀rẹ̀ sí í súnmọ́ ọn káa fi lè ríi dáadáa. Nígbà tí a súnmọ́ nkan náà dé ibi pé kò sí nkankan tó díwa lójú, tí a sì nwòó kedere ní iwájú wa, ìyanu gbáà ló jẹ́ fún wa. A wo arawa pé àbí irọ́ ni, kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ilé kan lá mà rí o. Irin ni wọ́n fí kọ́ ilé náà. Àmọ́ nkan tó jẹ́ ìyanu nlá fún wa ni pé ní àkọ́kọ́ ilé náà dàbí eni pé ó léfò lórí afẹ́fẹ́ ni! ṣùgbọ́n nígbà tí a wòó tí a tún-un wò, a ríi pé nṣe ni ilé náà fi igun kan kanlẹ̀. Àmọ́ o, igun kan tó fi kanlẹ̀ kò dín ìyanu náà kù rárá. Nítorí a wòó pé o yẹ kí ilé ọ̀hún wó lulẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ tó léfò. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Nṣe ni ilé náà dúró gbain-gbain bí igi osè ni. Kódà wọ́ tún ta okùn mọ́ abẹ́ ilé náà níbi to ti léfò, tí wọn sì ṣe ìjókòó olókùn sí i! A tún fojú inú ròó pé ẹni bá jókòó sórí okùn náà, àfi kí ilé wó lu olúwarẹ̀ pa.
Kíkọ́ tí wọ́n kọ́ ilé náà sí inú igbó tún yàwá lẹ́nù díẹ̀. A wò ráràrá bóyá a ó rí ẹnìkan níbẹ̀, ṣùgbọ́n ibẹ̀ dákẹ́ rọrọ ni. Àwa nìkan sì là wà ní àdúgbò náà. Ṣé wọ́n ní "igi gogoro má gúnmi lójú, àtòkèrè làá tí í wòó" àbí? Òun ló dífá fún wa lọ́jọ́ náà, táa fi tẹsẹ̀ mọ́nrìn kúrò nínú igbó náà, táa darí sí ìgbèríko táa fi ṣe ibùdó.
Nigbàtí a dé ìgbèríko náà ni a wá fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ará ìlú lẹ́nu wò nípa ilé tó nléfò nínú igbó. Ẹ̀rín ni wọ́n fi wá rín nígbàtí wọ́n ṣàkíyèsí pé ó bàwá lẹ́rù díẹ̀. Wọ́n sọ fún wa pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ilé-kíkọ́ kan ni wọ́n kọ́ ilé náà síbẹ̀. Wọ́n ní ara nkan tí ó nfa èrò wá sí ìlú àwọn nìyẹn. Kódà wọ́n ní ènìyàn lè sanwó ránpẹ́ kan tí ènìyàn bá fẹ́ dúró síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibùgbé. Nígbàtí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi dé'lé a se ìwádìí nípa ilé náà lórí Ayélujára. Bí àwọn ará ìgbèríko náà ti wí bẹ́ẹ̀ náà ló rí.
Àb'ẹ́ẹ̀ rí nkan? Yoòbá ní "Àìrìn jìnnà ni ò jẹ́ ká rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, táa bá rìn jìnnà à ó rí abuké erin". Yoòbá kú ọ̀rọ̀.

Comments
Post a Comment