Ata ju ata lọ

Ẹ wá wo orí ológbò látẹ o ẹ̀yin èèyàn mi! "Èwo lẹ tún rí o Alákọ̀wé?" Yó yẹ yín kalẹ́! Mo mà tún rí nkan o.

Lóòótọ́ àwa ọmọ Nàìjá a fẹ́ran ata, àgàgà àwa ti ilẹ̀ Oòduà. Ẹlòmíì a se'bẹ̀, a fi ata já a. Kódà a rí ẹni tí kò ní jẹun kankan àfi tí ata bá wà níbẹ̀. Dájú-dájú ìran jata-jata ni àwa ń ṣe.

Òun ni mo fi ń yangàn fún àwọn ọ̀rẹ mi kan nílẹ̀ yìí o. Mo wí fún wọn pé kòsí oúnjẹ kankan nílẹ̀ wọn tó láta to tiwa. Mo tún ṣakọ pé irúfẹ́ ata tí èmi Alákọ̀wé ò lè jẹ - wọn kò tí ì ṣẹ̀dá ẹ̀ nílẹ̀ yìí.

Àwọn òyìnbó dá mi lóhùn pé òtítọ pọ́nbélé ni mo sọ, n kò parọ́ rárá.   Wọ́n tún wípé kódà àwọn aláwọ̀ funfun tí mo rí yìí - tí àwọn bá ṣèṣì jẹ irú ata tí a ń wí yìí, ńṣe ni ojú àwọn á di pípọ́n kuku bí aṣọ àparò! Bẹ́ẹ̀náàni gbogbo ọ̀nàfun á máa ta àwọn bí ẹní máa kú ni. Wọ́n ní nítorí ìdí èyí ni àwọn kò ṣe kí ń jẹ ata. Pé tí oúnjẹ bá ti láta fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ báyìí, àwọn a yáa yẹra fún un.  Mo rín ẹ̀rín àrínbomilójú nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí tán. Kání àwọn babańlá wa mọ̀n níjọ́ kìíní àná ni, bóyá àwọn Gẹ̀ẹ́sì ò bá tí múnwa sìn.

Mo bá tún mú ìpanu aláta kan tí mo múdání, mo sọ ọ́ sẹ́nu kàló, mo rún un lẹ́nu wómú-wómú. Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹgbẹ́ mi aláwọ̀funfun náà. Wọn gbóríyìn fún mi, wọ́n wa ń wo èmi Alákọ̀wé gẹ́gẹ́ bí òrìṣà kan láàrin wọn.


Ní òjijì ni ẹnìkan bá dìde láàrin wọn. Ọmọ orílẹ̀èdè Ṣáínà ni onítọ̀hún ń ṣe. Jin ni orúkọ rẹ̀, èmi àti arákùrin náà sì ti mọ̀nrawa fún nkan bí ọdún kàn nípasẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ wa. Jin bá bọ̀ bí ẹní pòwe. Ó ní "ní ìlú afọ́jú, olójúkan ni ọba wọn".

Ẹ gbà mí o! Ta wa ló fún ará Ṣáínà lẹ́nu ọ̀rọ̀? Èmi náà bá dá lóhùn pé njẹ́ ó mọ̀n pé ṣàkì kìí ṣẹgbẹ́ ọ̀rá bí? Mo nawọ́ ìpanu aláta tí mo ń jẹ sí i - "ó dáa náà gbà èyí kí o tọ́ ọ wò. Ṣé tí ogún ẹ̀ni bá dáni lójú a fi ń gbárí ni?"

Jin kúkú kọ̀ ó l'óun ò jẹ ìpanu aláta. Ó ní kékeré nìyẹn. Kàkà kí ó jẹ, òwe ló tún pa. Ó tẹnu bọ̀rọ̀ ó wí pé "Àìrìnjìnnà làìrí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, tí a bá rìn jìnnà á ó rí abuké erin. N ó mú ìrẹ Alákọ̀wé dé ibi tí wọ́n ti ń jẹ ata gidi nílẹ̀ yìí, ìwọ yíò sì gba Ọlọ́run l'ọ́gàá! Ìwọ á gbà pé àti ṣàkì o, àti ọ̀rá o, ẹran abọ́dìí ni ọba gbogbo wọn"

Mo wí fún Jin pé tó bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ kó nìṣó níbẹ̀. Mo fọwọ́ sọ̀yà pé irúkírú oúnjẹ alátá tí wọ́n bá sè fún mi níbẹ̀, èmi Alákọ̀wé á jẹ ẹ́ láì mu omi kankan sí i.


Ẹbá ọ̀nà kékeré kan ní àdúgbò kọ́lọ́fín kan láàrìn gbùgbùn ilú Lọndọn ni ilé-oúnjẹ náà sápamọ́ sí.
Orúkọ rẹ̀ ni Chilli Cool. Orúkọ ọ̀hún sì fẹ́ dá'yà já'ni. Ata rodo ní ń jẹ́ Chilli. Àmọ́ ẹ̀rù ò b'odò, ibi líle làá ba ọkùnrin.

A wọlé a fi ìkàlẹ̀ lé e. Ìgbà náà ni Jin wí fún mi pé kí n má wùlẹ̀ wo ìwé-oúnjẹ́ tí wọn fún wa. Pé òun Jin ni yó yan gbogbo nkan tí màá jẹ. O ní ṣé mo rántí nkan tí mo sọ? "Tí ìwọ bá lè jẹun láì mu omi lóòótọ́, èmi Jin ọmọ ilẹ̀ Yiwu ní Ṣáínà ni yíò sanwó. Ṣùgbọ́n tí ìwọ Alákọ̀wé Yoòbá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ajẹ́pé mo rí oúnjẹ ọ̀fẹ́ jẹ nìyẹn nítorí ìwọ ni wàá tọwọ́ bọ àpò o". Èmi náà bá dá a lóhùn pé mo fara mọ́n ọn bẹ́ẹ̀. "Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, oun tó bá yá kìí tún pẹ́ mọ́n, oúnjẹ ọ̀hún dà? Ẹ gbé e jáde kí n máa báṣẹ́ lọ jàre!"

Nígbà tó yá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ń gbóòórùn nkan tó ń tasánsán bí ọbẹ̀ ata. Kíà ni wọ́n bá gbé àwọn oúnjẹ ọ̀hún wá lọ́kọ̀ọ̀kan. Ni nkan bá ṣe!


Ẹ wá wo ata ní onírúirú, ọlọ́kanòjọ̀kan àti oríṣìíríṣìí! Gbogbo irúfẹ́ ata tí Olódùmarè dá sí ilé-ayé ni wọ́n péjọ sínú àwo. Gbogbo wọn wá ń játùbú nínú omi ata, wọ́n ṣe àwọ̀ kàlákìní.

Ẹ̀rù Ọlọ́run sì bà mí. Oúnjẹ rèé àbí àtẹ aláta? Jin rẹ́rìn-ín músẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun lọ. "Óyá Alákọ̀wé oúnjẹ yá, àbí bóo ni?" Mo kúkú gbìyànjú ẹ̀. Mo fi ṣíbí tọ́ díẹ̀ sẹ́nu, ni òógùn bá bò mí, ahọ́n mi ṣe bí ẹní fẹ́ bó.

"Omí o!"

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá