Ebola



Mo kí gbogbo yín o. Ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ẹ sì kú àìfaraálẹ̀ náà. Olúwa yó máa fúnwa ní alékún okun àti agbára o.

Toò, ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò wá. Èé ti rí? Ọ̀rọ̀ Ebola yìí mà ni o. Kòkòrò búburú tí í fa àjàkálẹ̀ ààrùn. Kòkòrò tí kò gbóògùn.

Bóo la ti wá fẹ́ ṣe é o? Ibo là á gbe gbà? Àwọn oní Bókobòko níwá, Èbólà lẹ́hìn. Àfi kí Elédùà kówa yọ.

Àmọ́ ṣá, Yoòbá ti wípé ojú l'alákàn fi ń ṣọ́rí. Kí oníkálukú yáa tẹra mọ́n ètò ìmọ́ntótó rẹ̀. Kí ó sì máa ṣe àkíyèsí gbogbo nkan tí ń lọ ní'tòsí.

Orísìírísìí là ń gbọ́ nípa kí la lè ṣe láti dáàbò bo'ra ẹni. Àwọn kan ní omi gbígbóná àti iyọ̀ ni ká fi wẹ̀. Kíá ni àti mùsùlùmí àti kìrìstẹ́nì ń da omígbóná ságbárí. A tún gbọ́ pé orógbó tàbí obì ni àjẹsára tọ́n lè báni yẹra fún ààrùn Ebola. Wéré ni tọ́mọ́ndé tàgbà ń rún orógbó lẹ́nu bí i gúgúrú, tí wọ́n sì ń jẹ obì bí ẹní jẹ̀pà. Àt'orógbó àt'obì o, wọn ò ṣé rà lọ́jà mọ́n, ńṣe ni wọ́n gbówó lérí tete.

Bẹ́ẹ̀ rèé ènìyàn ò báà bẹ́ sínú àmù ọmígbóná oníyọ̀, kó jẹ́ orógbó agbọ̀n kan, kó sì jẹ obì tó kún apẹ̀rẹ̀. Tí olúwarẹ̀ bá ko Ebola, tí kò bá ṣe àfira wá nkan ṣe, ṣàngbà fọ́ nìyẹn - ó di gbére.

Èmi wí tèmi, àmọ́ ẹnu ọlọ́rọ̀ lọ̀rọ̀ ti ń dùn. Ẹ fetí sí ètò Yorùbá Gbòde níbi tí olóòtú Ṣọla Yusuf ti gba amòye onímọ̀ nípa Ebola, tí wọ́n sì làwá lọ́yẹ̀ dáadáa.

Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ o. Ìpàdé wa bí oyin o. Ire o.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?