Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!


Ẹkú ọjọ́ mẹ́ta o ẹ̀yin ènìà pàtàkì wọ̀nyí. Ṣe dáradára ni mo bá gbogbo yín o?
Ọ̀rọ̀ ọ t'òní á fẹ́ jọ yẹ̀yẹ́ létí ẹlòmíì, ṣùgbọ́n kìí ṣ'àwàdà rárá o. Ọ̀rọ̀ gidi ni.

Ẹ ní kílódé? Ẹ mà ṣeun o. Ebi ló pa mí ní ìrọ̀lẹ́ òní tó mún mi ya ilé oúnjẹ olókìkí nì tí wọ́n ń pè ní KFC. Adìẹ díndín ni wọ́n ń tà níbẹ̀. 'Tapátẹsẹ̀ ni wọ́n ń dín in. Tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́ ní ẹyọ-ẹyọ, ẹ lè rà á bẹ́ẹ̀. Bó sì jẹ́ àdàpọ̀ ẹsẹ̀ àti apá lẹ fẹ́, ìyẹn náà wà. Kódà wọn a tún máa ṣè'kan pẹlẹbẹ láti igbá-àyà adìẹ, wọ́n á tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ sí ààrin búrẹ́dì pẹ̀lú ẹ̀fọ́ díẹ̀ àti àwọn midinmíìdìn ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Àwọn olóyìnbó a máa pè'yẹn ní "Burger". Kiní ọ̀hún a máa wù'yàn jẹ o jàre. Àgàgà àwọn tí wọ́n fi ata sí dáadáa. Wọ́n tún ṣe'kan tó jọ dùndú anọ̀mọ́ tí wọ́n ń pè ní "fries". Kiní ọ̀hún a máa dùn tí wọ́n bá dín in gbẹ dáadáa. Parí-parí ẹ̀, ènìà tún lè fi ọtí ẹlẹ́ridòdò kan lé e. Gbogbo rẹ̀ á wá ṣe rẹ́gí-rẹ́gí l'ọ́nà ikùn. Ara olúwarẹ̀ a wá yá gágá.

Kí ló wá fa ẹjọ́ o Alákọ̀wé? Yó dára fún gbogbo yín o.

Ṣé ẹ rí adìẹ KFC yíì, wọn ò kàn kí ń dín in lásán o. Wọ́n á kọ́kọ́ fi àwọn èròjà kan pa á lára kí wọ́n to sọ ọ́ sínú agbada òróró gbígbóná. Àwọn èròjà wọ̀n-ọn nì ní wọ́n fún oújẹ wọn ní adùn tó dára dé ibi pé, wọ́n sọ ọ́ ní 'àjẹ-lá-ìka' - ajẹ́pé ení bá jẹ adìẹ díndín wọn, ńṣe ni olúwarẹ̀ á máa lá ìka tó fi mún adìẹ náà sẹ́nu nígbà tó bá jẹ ẹ́ tán. Nítorí ìdí èyí, KFC di gbajúgbajà, wọ́n di ọ̀kan nínú àwọn ilé-oúnjẹ aláràjẹ tó lókìkí jù ní gbogbo àgbáyé.

Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni àwọn èròjà náà dùn tó bẹ́ẹ̀, kí ló ṣe tí àwọn ilé-oúnjẹ ìyókù ò ṣe máa lò wọ́n se oúnjẹ tiwọn? Ìtàn ń bẹ níbẹ̀. Ṣé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní 'bí kò bá ní ìdí, obìnrin ò kí ń jẹ́ Kúmólú'. Ìdí abájọ ni pé, gbogbo àwọn èròjà náà, àti ètò bí wọ́n ṣe ń pò wọ́ pọ̀, nǹkan àṣírí ńlá ni. Láti ọdún 1930 títí dé ọjó òní, awo ńlá ló jẹ́ láàrin wọn. Ẹnìkankan ò sì tí ì já wọn.

Àmọ́ ṣá o, ṣé bí a bá gbìyànjú títí, tí a kò rí kókó tú, a ó fi kókó ọ̀hún sílẹ̀, a ó wàá okùn míì lọ? Ìyẹn ló dífá fún àwọn aládìẹ díndín 'yòókù, tí wọ́n dẹ́kun fífarawé KFC, tí wọ́n sì wá àwọn èròjà tiwọn lọ.

Ní tèmi o, mo ti jẹ adìẹ díndín níbòmíràn tọ́n dùn yùngbà dé'bi pé, ti KFC gangan ò dùn lẹ́nu mi mọ́n! Àgàgà lọ́dọ̀ àwọn ará Pakistan àti India. Wọn a máa fi ata sí oúnjẹ dáadáa bíi tiwa.

Lónìí, mo yà KFC lọ nítorí ebi ni. Mo ra itan àti igbá-àyà adìẹ, pẹ̀lú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ oújẹ kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú ife Pepsi tútù kan. Bí mo ṣe bù ú jẹ ni adìẹ náà kàn ṣ'ọ̀rá sìnkìn sí mi lẹ́nu. Kiní ọ̀hún ò tiẹ̀ ta rárá, ó wá rí ràṣì-ràṣì lẹ́nu. Nígbà tó ṣe mí bí ẹní fẹ́ bì, mo bá tọ́ pepsi díẹ̀ sẹ́nu. Pepsi náà dàbí èyí tí wọ́n ti ṣí sílẹ̀ látààná, kò tiẹ̀ ru rárá - ó kàn dà bí omi lásán. Èsùrẹ́ sì fẹ́ gbé mi. Mo yáa mọ̀'wọ̀n ara mi, mo dìde kúrò ni ìkọ̀ oújẹ wọn, mo gba Pizza Express kan tí ń bẹ ní ẹ̀bá ibẹ̀ lọ. Mò bẹ̀ wọ́n kí wọ́n bá mi rẹ́ ata rodo sórí Pizza mi o jàre. Wọ́n kúkú ti dámi mọ̀n níbẹ̀ pé jata-jata ni mo jẹ́.

Èrò tèmi ni pé, bíótilẹ̀jẹ́pé ilé-iṣẹ́ KFC fi dá wa lójú pé àwọn ò tíì pààrọ̀ àwọn èròjà tí wọ́n ń fi s'óúnjẹ láti ọdún 1930, kiní ọ̀hún ò dùn lẹ́nu tèmi mọ́n o. Ó ṣeéṣe pé ahọ́n ọ̀n mi ló ti yí padà, nítorí lóòótọ́ ni kiní ọ̀hún dùn sí mi nígbà kan rí. Tàbí pé, irọ́ ni ilé-iṣẹ́ náà ń pa fún wa. Bí o ti wù kí ó rí, ẹ ò yó rí mi níbẹ̀ mọ́n láti òní lọ.

Ẹ̀yin ńkọ́? Ǹjẹ́ ẹ ti jẹun ní KFC láìpẹ́ yìí bí? Báwo lẹ ṣe rí oúnjẹ wọn sí? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ o, ẹ fèsì kalẹ̀ o.

Toò, ó tún dìgbà kan ná o ẹ̀yin ẹ̀dá pàtàkì mi. Kí Olódùmarè dá wa sí o. Àṣe.

Comments

  1. inu mi dun pe mo ri awon ti o ni ife yoruba pupo bayi, ayomi si kun.
    Nje ti aye ba wa fub yi, inu mi a dun ka le jomitoro oro boya ari ona kan tabi meji ta le gba jo se awon ise kan papo. Oruko mi ni Olufemi adekoya. E si le kan si mi lori ero olufemiadekoya@ftlj5.com tabi +13472857401

    ReplyDelete

Post a comment

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá