Ìrìnkèrindò Moravia


Yoòbá ní àìrìnjìnnà ni kò jẹ́ ká rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Ẹ wo ibi Alákọ̀wé rìn dé tó fi rí abuké erin. Ìrìnkèrindò gidi rèé o, ẹ máa bá mi kálọ.

Ilẹ̀ kan ń bẹ láàrin gbùgbùn Úróòpù tí ń jẹ́ Moravia. Ilẹ̀ ọ̀hún kìkì òkè ni, ó sì kún fún àwọn igbó aginjù ńlá-ńlá àti adágún odò fífẹ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan.

Èmi Alákọ̀wé yín àtàtà, mo fi ẹsẹ̀ mi méjéèjì tí Elédùà fún mi rin àwọn òkè náà. Mo sọdá àwọn odò tí wọn kò jìn púpọ̀jù, mo sì rìn nínú àwọn igbó wọnnì pẹ̀lú. Ó wá ṣe bí ẹni pé èmi gan-an ni ògbójú ọdẹ nínú igbó Maravia. Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé bíótilẹ̀jẹ́pé mo rí àwọn ẹranko kọ̀ọ̀kan t'ọ́n ṣàjèjì sí mi, n kò fojú kan ẹbọra tàbí abàmì ẹdá kankan o :) . Ọpẹ́ ni fún Olódùmarè.

Àmọ́ ṣá, oríṣìíríṣìí lojú rí níbẹ̀ o. Nígbàtí mo dé ẹ̀bá igbó kan, mo ṣàdédé rí nkan tó jọ agbárí ìkookò tí ẹnìkan gbé kọ́ igi. Ó dẹ́ru báni púpọ̀. Nígbà tó tún ya mo tún ń wo nkankan lókèrè tó fẹ jọ òjòlá ńlá. Ó kù díẹ̀ kí n padà lọ́nà kí n tó rí i pé okun lásán ni mo rí.


Oríta mẹ́ta kan ń bẹ lọ́nà àbáwọ igbó ńlá náà. Gbogbo òkúta ilẹ̀ ibẹ̀ funfun gbòò bí iyọ̀. Àsìkò ìwọ́wé tó jẹ, àwọn ewé ti wọ́ dà sílẹ̀, wọ́n wá pọ́n kuku. Gbogbo rẹ̀ wá ń tàn winiwini nínú ìmọ́lẹ̀ oòrun. Ó wuyì púpọ̀, kódà nkan ẹwà gidi gan-an ni.



Lẹ́hìn wákàtí mélòókan mo tọ igbó ọ̀hún ja sí ilẹ̀ ọ̀dàn ńlá kan tó lọ gbansasa kọjá ibi tí ojú ẹni ríran dé. Òkè kékeré kan ń bẹ láàrin ilẹ̀ ọ̀dàn náà. Ní orí òkè náà ni mo ti rí nkan ìyàlẹ́nu. Ilé gogoro kan mà ni o.

Ilé ọ̀hún ga tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, n kò lè fojú rí òkè rẹ̀ láti ìsàlẹ̀. Ó tún wá ṣe ṣoṣoro lókè, ó dàbí ẹni pé ó fẹ́ gún ojú-ọ̀run lábẹ́rẹ́. Àwọn kan ti wí fún mi tẹ́lẹ̀ náà pé àràmàndà ni ilé ọ̀hún jẹ́. Àmọ́ tí wọ́n bá wípé "Ìròhìn ò tó àmójúbà" bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ yìí rí. Kíákíá ni mo bá tẹsẹ̀ mọ́n'rìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tọ ilé náà lọ.


Nígbà tí mo súnmọ́ ọ̀n díẹ̀ sí i, mo ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan èjèèjì tí àwọn náà ń tọ ilé gogoro náà lọ. Ní òjijì ni gbogbo wọn bá dúró, wọ́n gbójú sókè. Èmi náà bá wòkè pé kí wa ló dé?

Ẹ̀rù Ọlọ́run sì bà mí. Òjò ti ṣú dẹdẹ lójijì. Àwọn ìkúùkù-òjò sì ti bo bí ìdajì ilé náà lókè. Àrá sán kàáwòóóó! Òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Gbogbo wa bá bẹ́ sí eré sísá. A súré tete tọ ilé ọ̀hún lọ pé bóyá a lè rí ibìkan gọ sí kí gbogbo aṣọ wa má baà tutù tán.

Ṣùgbọ́n oun tó dẹ́rù Ọlọ́run bani lọ́jọ́ náà ni pé bí òjò ṣe ń rọ̀ lemọ́-lemọ́ lé wa lórí, bẹ́ẹ̀ oòrùn ń ràn kalẹ̀ níhà ibòmíràn, tí a sì ń wò ó lọ́ọ̀ọ́kán. Òṣùmàrè wá fà kàlákìní lójú ọ̀run. Ah! Ẹ̀yin èèyàn mi nkan ńbẹ o!


Nígbà tó yá a kúkú dé iwájú ilé gígá roro náà. Ẹ bi mí pé kíni ojú mi rí níbẹ̀ ẹ̀yin èèyàn mi? Gbogbo rẹ̀ ni n ó rò fún yín ní apá kèjì ìtàn yìí. Ẹ padà wá láìpẹ́. Ẹ yíò ka bambarì ìtàn.

Ẹ kú ojú lọ́nà o :)

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?