Iṣẹ́ ló ń ṣíwájú ìgbádùn


Wọ́n ní ẹni tó da omi sí'wájú, ẹnítọ̀hún yó tẹ ilẹ̀ tútù. Ìyẹn ni pé kí a tó jẹ ìgbádùn, iṣẹ́ ní í ṣíwájú ẹ̀.

Ọ̀rọ̀ yìí ló díá f'Álákọ̀wé lọ́jọ́ òní. Njẹ́ ẹni tó fẹ́ jẹ ọbẹ̀ ilá yíò kọ́kọ́ rẹ́'lá. Àbí ẹni tó fẹ jẹ àmàlà, kí ìgùnwọ́ olúwarẹ̀ yáa gbáradì nítorí ọmọrogùn àti ìkòkò ọkà wọn kìí ṣ'ọ̀rẹ́ arawọn.



Àmọ́ o, ẹni tó bá tẹra mọ́n'ṣẹ́, ó di dandan kó jẹ̀rè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Bótiwù kó roni lójú láti rẹ́ ilá, tàbí láti ro àmàlà, tí oúnjẹ bá dé'lẹ̀ tán ìgbádùn dé!


Ẹkú ìsinmi òní o. Ẹ bá mi're :)

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn