Pangram Yorùbá
Tí a bá wí pé "Ayára kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ aláwọ̀ èèpẹ̀ fò gborí ọ̀lẹ ajá kọjá". Kíni ìtumọ̀ èyí? Kò ní ìtumọ̀ kankan pàtó ní èdè Yorùbá. Ṣùgbọ́n ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, gbólóhùn pàtàkì gbáà ni. "The quick brown fox jumps over the lazy dog" ni ó túmọ̀ sí ní Gẹ̀ẹ́sì.
Ìdí tí gbólóhùn yìí fi ṣe pàtàkì ni pé ó jẹ́ nkan tí àwọn onígẹ̀ẹ́sì npè ní "Pangram". Ìyẹn ni pé nínú gbólóhùn kan ṣoṣo yìí, gbogbo álúfábẹ́ẹ̀tì Gẹ̀ẹ́sì ló péjọ síbẹ̀ láti A dé Z.
Kò sí irúfẹ́ gbólóhùn yí tó jẹ́ mímọ̀ pàtó ní èdè Yorùbá tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá gbólóhùn ọ̀hún ti balẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà, Moses Mabayọjẹ ló ṣe àgbékalẹ̀ gbólóhùn yìí sí orí ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́ tí nbẹ lórí Ayélukára tí wọ́n npè ní Wikipedia. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn àgbàlagbà Yorùbá, òwe àgbà kan ni alàgbà yìí gbéyọ tí wọ́n sì kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tí ó fi kó gbogbo álúfábẹ́ẹ̀tì Yorùbá mọ́ra, ṣùgbọ́n tí ìtumọ̀ rẹ̀ kò yí padà rárá. Ṣé Yoòbá ti wí tẹ́lẹ̀ pé òwe lẹṣin ọ̀rọ̀.
Gbólóhùn náà ni :
"Ìwọ̀fà ń yọ̀ séji tó gbojúmọ́, ó hàn pákànpọ̀ gan-an niṣẹ́ rẹ̀ bó dọ̀la".
Gbogbo álúfábẹ́ẹ̀tì Yorùbá mẹ́dẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni wọ́n péjọ sínú gbólóhùn yìí. Àb'ẹ́ẹ̀ rínkan?
Mo kí Alàgbà Mábayọ̀jẹ́ fún iṣẹ́ ọpọlọ tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ yí. Ẹlẹ́dàá ò ní jẹ́ kí àgbà àti ọ̀jọ̀gbọ́n ó tán nílùú o.

Comments
Post a Comment