Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rìn wá

Onírúirú, oríṣìíríṣìí àti ọlọ́kanòjọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá ṣe ṣ'ẹ̀dá ọmọ ènìyàn sí ilé-ayé. Ó wé Lágbájá ní àwọ̀ dúdú riri, Ó dá Tẹ̀mẹ̀dù ní aláwọ̀ ẹfun. Bí Ó ti dá kúkúrú ló dá gíga ẹlẹ́sẹ̀ gbọọrọ. Irun orí ẹnìkan a gùn a fẹ́lẹ́, ti ẹlòmíràn a sì hunjọ bíi kàìnkàìn. Irun lámọín pupa yòò bí iná tí ń jó, irun làkásègbè àfi bí adé òwú dúdú. Aṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn dá abapá tínrín abẹsẹ̀ tínrín bíi ẹyẹ lékeléke. Kò sì ṣàìdá alápá ńlá ẹlẹ́sẹ̀ gòdògbà bí àjànàkú.

Àbí ẹ kò rí imú àwọn kan pẹlẹbẹ bí ìgbákọ? Ó ṣeé kọ àmàlà ní'kòkò. Bẹ́ẹ̀ imú àwọn míì sọsọrọ bí akọ́rọ́ tó ṣeé ká ọsàn lórí igi. Ètè ńkọ́? A rí èyí tó fẹ́lẹ́ bí abẹ̀bẹ̀. Òmíì sì rèé kíki pọ́npọ́n bíi pọ̀nmọ́. Ẹ wo onírúirú agbárí ọmọ ẹ̀dá. Òmíì róbó-róbó bí àgbọn, bẹ́ẹ̀ Ẹlẹ́dàá fi ìpàkọ́ lànkọ̀ ta ẹlòmíì lọ́rẹ. Orí a wá ṣe rìbìtì bí Olúmọ, orí enítọ̀hún a wá máà júbà orígun mẹ́rẹ̀rin ayé bí ó ti ń rìn lọ.

Gíga sókè ọmọ ènìyàn, àṣé kìí ṣe nípasẹ̀ ẹsẹ̀ gígùn nìkan. Olódùmarè tún ṣ'ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ kúkúrú, Ó wá fi ọrùn gígùn dá a lọ́lá. Olúwarẹ̀ a wá jọ ògòngò baba ẹyẹ. Ẹ̀dá míràn dẹ̀ rèé kò ní ọrùn kankan rárá. A jẹ́ pé enítọ̀hún di ẹbí ìjàpá tìrókò ọkọ yáníbo.

Ọ̀kan ṣoṣo ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Olódùmarè ṣe ẹ̀dá olúkálukú. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rìn wá, gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá kan, ilé-ayé la ti pàdé.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!