12/12/12
Òní jẹ́ ọjọ́ kejìlá, oṣù kejìlá, ọdún kejìlálélẹ́gbàá. Káàkiri àgáyé ni àwọn èèyàn dá ọjọ́ òní sí ní ọlọ́kan-òjọ̀kan nítorí bí ònkà ọjọ́ náà ṣe báramu rẹ́gí-rẹ́gí.
Ìyàtọ̀ wà láàrin bí wọ́n ṣe nkọ ọ́ ní ìlànà Amẹ́ríkà àti ti àwọn Oríẹ̀èdè ìyókù. Ní Amẹ́ríkà, ònkà oṣù ni wọ́n máa nkọ ṣáájú ònkà ọjọ́. Ní gbogbo ibòmíràn ẹ̀wẹ̀, ònkà ọjọ́ ní í ṣíwájú kí ti oṣù tó tẹ̀lé e. Àmọ́ lọ́jọ́ òní, ìlànà méjéèjì náà tún báramu. Tí aago méjìlá bá tún wá kọjá ìṣẹ́jú méjìlá àti aaya-ìṣẹ́jú méjìá, gbogbo rẹ̀ a wá báramu rẹ́gí-rẹ́gí tán pátá-pátá poo.
Wọ́n ní àkókò kò dúró de ẹnìkan. Gbàrà tí àkókò yìí bá dé, ó ti tún sáré tẹ̀ síwájú, ó nbá'bi tiẹ̀ lọ. Ó tún di ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún, ní ọjọ́ kíní, oṣù kíní ọdún 2101, tí kíkọ sílẹ̀ rẹ̀ á jẹ́ 01/01/01.
Àyàfi ọmọ tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sáyé, àti àwọn tí Olódùmarè bá fún ní ẹ̀mí gígùn gbọ̀rọ̀-gbọrọ, ṣàṣà ni ẹni tí ò ní tíì jẹ́ ìpè Ẹlẹ́dàá rẹ̀ kí ìgbà náà tó dé o. Ìyẹn tí ayé gan-an kò bá tíì parẹ́.
Comments
Post a Comment