Ojúmọ́ gígùnjùlọ


Àwọn àgbà Yorùbá àtijọ́ a máà sọ̀rọ̀ kan. Wọ́ ní "oòrùn ló ni ọ̀sán, òṣùpá lo ni òru". Òótọ́ ni. Àmọ́ ìyẹn lọ́dọ̀ tíwa lọ́hùún ni o.

Ẹ jẹ́ mọ̀n pé àwọn ibìkan ń bẹ tí oòrùn kò ní wọ̀ rárá lónìí? Bẹ́ẹ̀ni. Ajẹ́pé lọ́dọ̀ tiwọn níbẹ̀, àti ọ̀sán gan-gan o, àti gànjọ́ òru, ìkáwọ́ oòrùn ló wà. Ìyẹn lórí eèpẹ̀ àgbálá ayé wa yìí náà o.

Ní ìlú ọba níhìín, fún wákàtí mẹ́rìndínlógún àti ìṣẹ́jú méjìdínlógójì ni oòrùn yíò ran ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ yanyanyan léwa lórí kó tó wọ̀ ni nkan bí i aago mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún.

Aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni mo ya àwòrán yìí lónìí, àmọ́ ẹ wo bí oòrùn ti mún. Kódà ní ìta gbangba ńṣe ni oòrùn kanni látàrí gbọ̀ngbọ̀n.

Ìdí abájọ ni pé òní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje ọdún ni ojúmọ́ gígùnjùlọ lọ́dún ní ìhà àríwá àgbáyé. Mo ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí rí níbìkan.

Òní tún bọ́ sí ọjọ́ Àbámẹ́ta tí í ṣe ọjọ́ ìgádùn kẹlẹlẹ. Ní tèmi Alákọ̀wé, fàájì ni mo wà o jàre.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?