Ọjọ́ mẹ́wàá péré lókù

Àwọn ẹ̀yà ayé àtijọ́ kan tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Maya sọ wipé ayé á parẹ́ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejìlá ọdún 2012. Ọjọ́ mẹ́wàá òní ni ọjọ́ náà pé o! Njẹ́ lóòótọ́ ni ayé máa parẹ́ bí?

Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀yà Maya ti parẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé ní nkan bíi ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn, òkìkí wọn ti kàn gidi gidi lọ́dúnnìí nítorí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọn yìí. Lóòtọ́ ná, bí eré bí àwàdà ni púpọ̀ nínú wa fi nṣe, àmọ́ àwọn kan ní ìgbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, wọ́n ti lọ́ ba sórí àwọn àpátá nlá-nlá. Irú èyí nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́-lọ́wọ́ ní ìlú Faransé, Séríbíà, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní tèmi o, mo mọ̀n dájú pé kòs'ẹ́ni mọ̀la. Ṣùgbọ́n ó múmi ronú pé tí ayé bá máa parẹ́ kí Kérésì tó dé, njẹ́ èmi ti ṣetán láti pàdé Ẹlẹ́dàá báyìí? Àti pé kíló kù nlẹ̀ tí ng kò tíì ṣe?

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!