Ọdún tuntun wọlé
Yorùbá bọ̀ ó ni "...ogún ọdún ń bọ̀ wá d'ọ̀la". Ọjọ́ wo náà la bẹ̀rẹ̀ 2013 ná tó ti yáa tún káṣẹ̀ńlẹ̀ báyìí? Ab'ẹ́ẹ̀rí nkan? A jẹ́ pé àsìkò kò dúró de ẹnìkan. Ayé ń yí lọ biribiri bí òkúta, àwa ẹ̀dá ń tọ̀ ọ́. Ọdún tuntun tó wọlé dé yìí, á mú're tọ̀wá wá. Ọdún á yabo fún gbogbo wa o. Mo kí gbogbo yín kú àlàjá 2013. Ẹ sì kú ọdún tuntun 2014!
Ire o!
Ire o!
Comments
Post a Comment