Àdìtú Stonehenge




Ní ìyálẹ̀ta ọjọ́ òní ni àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí ti jí dé ibi àkójọpọ̀ okúta ayérayé nì tí wọ́n ń pè ní Stonehenge.

Ìdí abájọ ni pé lọ́jọ́ òní, tí í ṣe ọjọ́dọ́gba, ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé. Ìyẹn ni pé ìgbà ọ̀gìnìntìn ti ré kọjá, a ti bọ́ sí ìgbà ọ̀tun.

Ní ayé àtijọ́ kí ẹ̀sin Kìrìstẹ́nì tó dé'lẹ̀ yìí, àwọn náà ní ẹ̀sìn ìbílẹ̀ tiwọn. Ọ̀kan nínú àwọn àjọ̀dún tó rọ̀ mọ́n ẹ̀sìn náà ni àjọ̀dún òrìṣà Eostre.

Eostre ni òrìṣà nkan tuntun, ìgbà tuntun, bí ọmọ bíbí. Ìdí èyí ni a fi rí orúkọ abo òrìṣà yìí nínu "E(o)strogen" fún àpẹrẹ. Ẹ ka nkan tí mo kọ nípa Eostre àti Easter
Stonehenge ti pẹ́ ní orílẹ̀ yìí tó jẹ́ pé a kò lè sọ pàtó pé àwọn báyìí ni wọ́n kọ́ ọ síbẹ̀. Orísìíríṣìí ìtàn atẹnudẹ́nu ló dárúkọ rẹ̀, àmọ́ kòsí ẹni tó mọn òdodo ọ̀rọ̀.

Bótiwù kó jẹ́, nkan ìyanu gidi ni òkuta yìí. Lọ́jọ́ òní, àti lọ́jọ́dọ́gba ìgbà ìwọ́wé, ìlànà tí oòrùn tọ̀ láti ilà dé ìwọ̀ lókè ọ̀run bá ti Stonehenge mu rẹ́gí-rẹ́gí nílẹ̀. Èyí fi hàn wá pé làákáyè ńlá ni àwọn tí wọ́n kọ́ ọ ní. Àti pé wọ́n ní ìmọ̀jinlẹ̀ gan-an ni nípa ojú ọ̀run.

Àwọn òkúta ọ̀hún tóbi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, nkan àdìtú ni bi wọ́n ṣe gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà láàrin ọ̀dàn - tí kò sí àpata kankan ní ìtòsí. Ó ṣe èmi Alákọ̀wé gan-an ní kàyéfì ní ìgbá tí mo f'ojú mi kòró-kòró kàn án. N kò rí nkankan sọ, àfi pé Ọlọ́run tóbi l'ọ́ba.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?