Mandela oníwà pẹ̀lẹ́ wàjà

Ikú bàjẹ́. Nígbà míì a fi ẹni ibi sílẹ̀, a mú ẹni ire lọ. Àmọ́ lẹ́yìnọ̀rẹyìn o, kòsí ẹni tí kò ní kú, ti oko baba rẹ̀ ní di ìgbòòrò - gẹ́gẹ́ bí òwe Yoòbá kan - a dífá fún Rolihlahla tó w'àjà l'ọ́sẹ̀ tó kọjá, ti gbogbo aráyé ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

Ẹni ire gbáà ni ikú mún lọ l'ọ́tẹ̀ yìí o. Báwo la ṣe lè ṣe àpèjúwèé olóògbé Mandela ná? Tí a bá pè é ní Ìlúmọ̀míka, bí ẹní tẹ́mbẹ́lú rẹ̀ ni. À bá pè é ní Gbajúmọ̀, bí kìí ṣe bí ẹní dá a kéré ni. Kò kúkú l'áàńṣàpèjúwèé kankan ẹ̀yin èèyàn mi. Òdú ni bàbá yìí, kìí ṣe ẹni tí olóko kò mọ̀n. Ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ ni alàgbà yìí nígbà ayé rẹ̀, kìí ṣ'àmọ̀ fún olódò. Iṣẹ́ ribibi lọ́ ṣe fún ànfàní àwa adúláwọ̀ káárí ayé tí kò ṣé fi ẹnu sọ tán.

A kò lè gbàgbé rẹ láíláí Mandela. Pàápàá n ó máa ṣe ìrántí ọjọ́ tí mo rí ọ lójúkorojú ní Orílẹ̀ Senegal láìpẹ́ tí wọ́n tú ọ sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Èmi àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí a wá pàdé rẹ lọ́jọ́ náà. Àwọn tí o fún ní ìmísí kò l'ónkà.
Ọ̀la ni wọ́n máa sin olóògbé àgbàlagbà aṣíwájú yìí. Kí Ọlọ́run dẹ'lẹ̀ fún ẹni ire. Ajẹ́pé ó di gbére, ó di àrìnàkò, ó di ojú àlá. Má jẹ ọ̀kùn, má jẹ ekòló, oun tí wọ́n bá ń jẹ ní àjùlé ọ̀run ni kí o máa bá wọn jẹ. Kò séni tí kò ní jẹ́ ìpe Olódùmarè. Ọ̀run nìkan ni àrèmabọ̀.

Tata Madiba Rolihlahla Mandela. Sùn're o!

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?