Kọfí ab'òdòdó lórí

Àṣà kan wà ní'lẹ̀ yìí tó jọ mí lójú. Àṣà ọ̀hún ni bí wọ́n ṣe máa ń dárà sí oúnjẹ àti oúnmu wọn. Pàápàá ní àwọn ilé-oújẹ, gbogbo nkan tí ń bẹ níbẹ̀ á wá máa ṣe kánmi-kànmì-kánmi, á wọ̀nni lójú gbáà. Tí olúwarẹ̀ ò bá ṣọ́ra, èèyàn á kó gbogbo owó ọwọ́ ẹni fún wọn níbẹ̀.

Ẹ̀yin ẹ wo àwòrán kọfí tí mo yà ní ìjẹta. Ẹ wo bí wọ́n ṣe dárà sí i lórí bí ẹni pé ọba kan ló fẹ́ mu ú. Ìkẹ́ àti ìgẹ̀ gidi ni wọ́n fi pò ó fún mi. Òun ni mo fi yà á l'áwòrán kí n tó mu ú o jàre. Kódà nígbà ti mo mu ú tán, wéré ni mo tún rà'míì mu. Otútù ń bẹ níta n kò sì re'bìkan :)

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?