Khoklaki
Ní Rhodes, tí í ṣe erékùṣù Greece kan, wọ́n ní àṣà ìbílẹ̀ kan tó wu'ni púpọ̀. Àṣà náà jẹmọ́ iṣẹ́ ọnà af'òkúta ṣe ni. Khuklaki ni wọ́n npèé. Khuklaki jẹ́ ọnà ìṣelẹ̀lọ́ṣọ̀ọ́. Inú ilé pàtàkì bíi ilé ìjọ́sìn tàbí ilé ọlọ́lá ni Khoklaki yìí máa ṣába wà.
Irúfẹ́ òkúta wẹ́wẹ́ méjì ni wọ́n fi nṣe Khoklaki. Òkúta dúdú àti funfun. Wọ́n á to àwọn òkúta wọ̀nyí sílẹ̀ ní ẹyo kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà àrà tí ó wù wọ́n. Ìgbà míràn wọ́n lè fi ya àwòrán sílẹ̀ tàbí kí wọ́n kàn ṣe é kàlákìní tí á dùn ún wò dáradára.Ẹwà gidi ni ọ̀ṣọ́ ilẹ̀ yí nbù kún ilé. Ó sì tún nmú ilé tutù- eléyìí wúlò púpọ̀ ní ìgbà oru. Àwọn òkúta tó dán dáradára nìkan ni wọ́n nlò. Wọ́n sì máa ntò wọ́n jẹ́ẹ́jẹ́ kí wọ́n fi gún régé ki ilẹ̀ ọ̀hún sì tẹ́jú pẹrẹsẹ dáradára. Èyí ṣe pàtàkì nítorí inú ilé ni wọ́n nṣábà má nṣe é sí. Kí ènìà lè fi rìn nínú ilé láì bọ bàtà, kí òkúta má gún'ni l'ẹ́sẹ̀.
Comments
Post a Comment