Kẹ̀kẹ́ Marwa
Yàtọ̀ sí Ọkada tí í ṣe kẹ̀kẹ́ akérò alùpùpù ní Naija, kẹ̀kẹ́ Marwa - kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta ní í ṣe. Kẹ̀kẹ́ náà ti gbajú-gbajà ní ìlú Èkó àti awọn ìlu nlá-nlá kọ̀ọ̀kan káàkiri Naija. Lati orúkọ Mohammed Buba Marwa tí ó jẹ́ gómìnà Èkó nígbàkan ni orúkọ kẹ̀kẹ́ yìí ti jẹyọ.
Àwọn òpópónà àti títì kékeré nìkan ni òfin gba kẹ̀kẹ́ Marwa láàyè àti rìn. Ìdí ẹ̀ ni pé kò lágbára títì nlá rárá. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ nígbàtí akérò kan ṣàìgbọràn, tí ó ngbé èrò lọ lórí títì nlá tó lọ́ sí Ibadan láti Èkó. Ọkọ̀ akẹ́rù gbàngbà kan sáré kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Atẹ́gùn ọkọ̀ akẹ́rù náà lásán ló fẹ́ kẹ̀kẹ́ Marwa kúrò lójú títì tó fi forí sọ òpó kan, tí awakẹ̀kẹ́ àti àwọn èrò fi ara pa.
Nkan bí ọdún méjì sẹ́hìn ni mo ya àwòrán yìí ní àdúgbò Èbúté Mẹ́ta ní ìlú Èkó. Bíótilẹ̀jẹ́pé púpọ̀ nínú àwọn kẹ̀kẹ́ Marwa náà ti gbo ti wọ́n ti fẹ́ẹ̀ẹ́ bàjẹ́, tí wọ́n sì rí jáku-jàku, wọ́n kópa pàtàkì nínú ètò-ìrìnsẹ̀ àwọn ará ìlú, pàápàá jùlọ fún àwọn mẹ̀kúnù. Àti pé bí wọ́n ṣe kùn wọ́n ní ọ̀dà àláwọ̀ kánnáà jẹ́ kí wọ́n dùn-ún wò lójú. Ní èrò tèmi o, wọ́n bu ẹwà kún ìlú Èkó rẹpẹtẹ!

Comments
Post a Comment