Kẹ̀kẹ́ amárale koko

Ṣebí àwọn ọmọdé ni wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́? Àgbà tí ń gun kẹ̀kẹ́, àfi tí enítọ̀hún bá jẹ́ ẹlẹ́mu. [Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, báwo gan-an ni àwọn ẹlẹ́mu ṣe ń gbé adúrú ẹmu yẹn káàkiri lórí kẹ̀kẹ́, tí akèrègbè ò bọ́ fọ́. Ọ̀rọ̀ ọjọ́ mìíràn nìyẹn.]. Àti pé, ojú ẹni tí ìyà ń jẹ ni wọ́n máa ń ṣábàá fi wo ẹni tí ń gun kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá. Bí ẹni pé enítọ̀hún kò ní owó làti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Nítorí ìdí èyí, kẹ̀kẹ́ gígùn kò wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yoòbá.

Ní abúlé, àti ìgbèríko, a lè rí àwọn àgbà tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ lọ s'óko tí ọ̀nà bá jìn. Àmọ́ ní'lùú ńlá bí Ìbàdàn, ewú ńlá ń bẹ lójú títì fún oníkẹ̀kẹ́. Yàtọ̀ fún ìwàkuwà, kò sí ìlànà àtì ètò kankan fún awákẹ̀kẹ́ lójú ọ̀nà.

Ní'lẹ̀ yí kọ́! Kẹ̀kẹ́ jẹ́ nkan pàtàkì gidi fún wọn níbí. Kódà, ètò ìrìnsẹ̀ tí ìjọba pèsè fún ará ìlú - kẹ̀kẹ́ ń bẹ níbẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ ni wọ́n gbójú lé kẹ̀kẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀ná tí wọ́n fi ń dé ibiṣẹ́ wọn lójoojúmọ́. Tọmọdé tàgbà sì ní. Àwọn ọ̀dọ́langba náà gbé kẹ̀kẹ́ wọn sí ipò pàtàkì. Àti ọ̀gá ibiṣẹ́, àti ìránṣẹ́ kẹ̀kẹ́ ni ọ̀pọ̀ wọn ń gùn káàkiri bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní'lé.

Idí abájọ ni pé ètò tó péye wà fún awakẹ̀kẹ́ lójú títì. Níbìkọ̀ọ̀kan, nṣe ni wọ́n fa ààlà s'ójú ọ̀nà, tí wọ́n ya ọ̀nà kẹ̀kẹ́ s'ọ́tọ̀, tí wọ́n kùn ún ní ọ̀dà tirẹ̀ fún àkíyèsí àwọn awakọ̀ pé ọ̀nà awakẹ̀kẹ́ rèé o. Èyí dín ewu kù púpọ̀ fún ẹni tí ń gun kẹ̀kẹ́ lójú títì. Bẹ́ẹ̀náàni ọ̀pọ̀ ènìà ló ka kẹ̀kẹ́ gígùn kún eré-ìdárayá òòjọ́. Ó dára púpọ̀ fún ara ẹni, ó sì fúnni ní àlékún ìlera tó yànjú. Ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ lójoojúmọ́ tó tún sanra ṣọ̀wọ́n. Ajẹ́pé enítọ̀hún a yẹra fún àwọn àìsàn tó rọ̀mọ́ sísanra bíi ẹ̀jẹ̀-ríru àti ọ̀rá-ẹ̀jẹ̀.

Kẹ̀kẹ́ dára púpọ̀. Ó dùn ún gùn, a sì máa mú ara ẹni le kokooko bí ọta. Àwọn àwòrán kẹ̀kẹ́ tí mo yà láàrìn ìgbòro ni ìwọ̀nyí. Èyí tó mú mi rẹ́rìn-ín ni àwòrán olóògbé àrẹ́ Líbíà nì tí ń gun kẹ̀kẹ́ ọmọdé tí ẹnìkan fi se araògiri lẹ́ṣọ̀ọ́.
 

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!