Ìwé Afọ́jú
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan báyìí nínú ọkọ̀-ojúurin abẹ́lẹ̀ ní ìlú Paris, ọ̀gbẹ́ni afọ́jú kan fẹ̀lẹ̀ jókòó sórí ìjòkó tó kọjú sí mi. Ọjọ́-orí ọkùnrin náà a jẹ́ nkan bíi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n. Ẹ̀yà adúláwọ̀ ni ọkùnrin náà jẹ́. Enìyàn kúkúrú sì ni. Kòsí ẹnikẹ́ni tí ó nràn án lọ́wọ́, kò sì ní ajá-afọ́jú rárá, àfi ọ̀pá-afọ́jú tí o mú dání. Síbẹ̀-síbẹ̀ afọ́jú náà wọ ọkọ̀ akérò láìsí ìṣòro kankan.
Nígbà tó ṣe díẹ̀ tí a ti wà nínú ọkọ̀ náà, mo ṣe àkíyèsí pé afọ́jú náà nrọra rẹ́rìn-ín sí'ra rẹ̀. Kò dẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tó nsọ̀rọ̀ síi. Àmọ́ nígbà tí mo wo ibi ọwọ́ rẹ̀ wà, mo rí kiníkan pẹlẹbẹ tó gbé lé itan, tí ó nfi àwọn ìka ọwọ́ rẹ̀ kan. Kíni ọ̀hún dàbí ìwé ṣùgbọ́n tí wọn kò kọ nkankan sí. Nígbà ti mo wòó dáadáa ni mo wá rí i pé wọ́n lu àwọn ihò wíní-wíní sí gbogbo ojú ìwé náà. Àmọ́ ẹ̀hìn ojú ewé ìwé ni wọ́n lu'hò sí; ajẹ́ pé ní iwájú ojú-ewé ìwé, ihò kọ̀ọ̀kan rọra lé sókè. Lílé sókè àwọn ihò náà ni afọ́jú nfi ọwọ́ kàn lójú ewé ìwé náà.
Kí wá ló fa ẹ̀rín-àdárín afọ́jú? Ìwé mà ló nkà o. A jẹ́ pé ó ka nkan tó pàá lẹ́rìn-ín nínú àkọsílẹ̀ tó nkà ni. Báwo wá ni afọ́jú ti nrí ìwé kà? Àbí ojú kọ́ la fi nkàwé ni? Ìdí abájọ ni pé àwọn ihò ojú-ewé náà, álúfábẹ́ẹ̀tì àti ònkà afọ́jú tí wọ́n npè ní Braille ni wọ́n jẹ́. Ọ̀gbẹ́ni Loiuse Braille tí í ṣe ọmọ orílẹ̀èdè Faransé ló ṣètò álúfábẹ́ẹ̀tì yìí fún àwọn afọ́jú ní ọdún 1821. Òun gangan kọ́ ló kọ́kọ́ ṣẹ̀dá irúfẹ́ ọ̀nà àti kàwé báyìí o. Ọ̀gbẹ́ni Charles Barbier láyé ààrẹ Napoleon Bonaparte ló kọ́kọ́ ṣe irú ẹ̀. Napoleon paá láṣẹ fún àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀ orílẹ̀èdè rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọ̀na tí àwọn jagunjagun òun lè fi máa kàwé nínú òkùnkùn láì tan iná kalẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Barbier ló dáhùn ìpèníjà yìí nígbà náà. Méjìlá-méjìlá ni ó to àwọn ihò tiẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. Sùgbọ́n nígbà tí àwọn jagun-jagun ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀, wọ́n kọ̀ọ́. Wọ́n wípé ó ti ṣòro jù látì kà nítorí ihò méjìlá ti pọ̀jù láti fi ìka ènìyàn kàn lẹ́ẹ̀kannáà. Lẹ́hìn ìgbà yí ni Ọ̀gbẹ́ni Barbier bá Ọ̀gbẹ́ni Braille pàdé ní ìlú Paris ní ọdún 1821 nígbàtí ó ṣe àbẹ̀wò ló sí ilé-ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú.
Louise Braille ló wá ṣe àtúnṣe sí ètò ihò-títò náà. Ó dín in kù sí ihò mẹ́fà-mẹ́fà, ó sì ṣé e to fi bá álúfábẹ́ẹ̀tì Faransé mu. Ìdí èyí ni wọ́n fi npèé ní Braille. Ọdún 1905 ni wọ́n tó ṣe irúfẹ́ rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Láyé òde òni o, Braille yìí tí wọ́pọ̀ lóríṣìíríṣìí èdè káàkiri àgbáyé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé sì ni wọ́n ti fi Braille tẹ̀ jáde fún ẹ̀kọ́ àti ìgbádùn àwọn afọ́jú. Eléyìí tún fún àwọn afọ́jú ní ànfàní àti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè, tàbí láti ka ìwé ẹ̀sìn wọn bíi Bíbélì àbí Àlùkùránì.
Kódà, ní àwọn orílẹ̀èdè tó lajú dáadáa, àwọn òfìn kọ̀ọ̀kan wà láti mú ìrọ̀rùn bá àwọn àkàndá ẹ̀dá bí àwọn afọ́jú. Nínú àwọn òfin wọ̀nyí ni pé kí wọ́n máa kọ Braille sára àwọn nkan bíi agolo òògùn, kí àwọn afọ́jú fi lè ríi kà fúnra wọn. Bẹ́ẹ̀náàni onírúirú ẹ̀rọ ìgbàlódé ti njáde fún àwọn afọ́jú. Ẹ̀rọ ayárabíàṣá oní Braille náà nbẹ!
Àṣé bí ọkùnrin afọ́jú náà ṣe nkàwé lọ, ó tún fi etí sílẹ̀ sí ìkéde awakọ̀ èrò. Nígbà tó yá ló bá yára palẹ̀ ìwé rẹ̀ mọ́, ó mú ọ̀pá rẹ̀, ó dìde ó rìn tààrà jáde kúrò nínú ọkọ̀ náà láìsí ìràlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Èmi ntèmi, ọkọ̀ ti kọja ibi tí mò nlọ. Mo ti wòran lọ.

Comments
Post a Comment