iPhone Fọ́
Ní ọdún mélòókan sẹ́hìn, ẹni bá fẹ́ràn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, nṣe ni ó ń kó wọn ká lóríṣìíríṣìí ni. Tí ẹ bá yẹ àpọ̀ enítọ̀hún wò, ẹ ó rí ẹ̀rọ ayàwòrán, ẹ̀rọ agbórinsétí alágbèéká, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ ní òde òní, àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tí wọ́n ń ṣe jáde ti gba'ṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ìyókù ẹgbẹ́ ẹ wọn o. Pàápàá jùlọ iPhone àti àkójọpọ̀ àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tí irúfẹ àìrídìmú inú wọn jẹ́ Android. A jẹ́ pé ẹ̀rọ kan ṣoṣo yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń gbé káàkiri. Bí a fẹ́ báni sọ̀rọ̀ ni, òun ni. Bí a fẹ́ yàwòrán ni, òun náà ni. Ìgbórinsétí nkọ́, kòsí ẹ̀rọ míì mọ́n àf'òun. Kódà, ònu ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń yẹ Ayélujára wò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rọ ayárabíàṣá wọn.
Njẹ́ mo ti wí ní ìgbàkan rí pé iPhone ni èmi gan-an alára ń lò. Gbogbo nkan sì ni mò nlò ó fún. N kò wọ ago-ọwọ́ mọ́. Orí rẹ̀ ni mo ti ń wò oun tí ago wí, òun sì ló ń jí mi láràárọ̀. Ìnú ẹ̀rọ yìí ní mo máa ń kọ gbogbo ètò sí, òun sì ni í ṣe atọ́kasọ́nà tí mo bá wà ní agbègbè ibi tí n kò mọ̀, kí n má baà sọnù. Tàbí tí mo bá ń wa'kọ̀ lọ sí ibi tí n kò dé rí. Òun ni ẹ̀rọ ayàwòrán mi. Òun ni ẹ̀rọ ìfìwéránṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni òun ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fún mi ní ìgbà gbogbo. Ọpẹ́lọpẹ́ ọpọ́n-ìtẹ̀wé Yorùbá tó tún ń bẹ lórí ẹ̀, òun ni mo fi ń kàn sí ẹ̀yin olùkàwé mi gbogbo, yálà ní ìhà'hín ni tàbí lórí Twítà. A jẹ́ pé kòrí-kòsùn gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ èmi àti iPhone mi jẹ́ o.
Arẹwà ẹ̀rọ ni iPhone jẹ́. Ìṣẹ́ ọnà gbáà ni ìṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́. Funfun rẹ̀ wà, àmọ́ dúdú bíi kóró isin ni ẹ̀rọ tèmi. Adúmáadán gidi ni nítorí pé dígí ni wọ́n fi ṣe iwájú àti ẹ̀hìn rẹ̀, wọ́n wá fi irin alárà yí i po. Sùgbọ́n ẹwà rẹ̀ yìí náà ló ṣ'àkóbá fún un o! Kàkà kí n wọ̀ ọ́ lẹ́wù tàbí kí n tì í bọ́'nú àpò fún ìdáàbò bò ó, nṣe ni mo fi sílẹ̀ ní ìhòhò. Aṣọ-káṣọ, àpò-kápò kò bá wù ó dára tó, á bu ẹwà iPhone kù ni. A jẹ́ pé nígbà tí ó ṣèṣì jábọ́ lọ́wọ́ mi níjọ́kan, tí ó sì balẹ̀ sórí àwọn òkúta, iwájú rẹ̀ tí í ṣe dígí kàn fọ́ ni. Ọpẹ́lọpẹ́ irin tí wọ́n fi dì í pọ̀, kò bá fọ́n ká pátápátá ni. A ò bá máa wá ṣa èrúnrún rẹ̀ nílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Báyìí-báyìí ó ti wà ní ibiṣẹ́ àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ náà. Wọ́n á gbìyànjú láti tún un ṣe. Tí wọn kò bá rí i tún ṣe, wọn á fi tuntun irú rẹ̀ ránṣẹ́ sí mi. Ìdí abájọ ni pé ilé-iṣẹ́ ìfowópamọ́ ti mo ń lò máa ń yọ eélòó kan nínú owó mi lóṣooṣù. Owó yìí jẹ́ aṣèdúró fún àwọn irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí. Iṣẹ́ ńlá ni kiní bíntín yìí ń ṣe fúni o. Ó di ìgbà ti ọwọ́ ẹni ò bá tó o mọ́ kí olúwarẹ̀ tó mọ iyì rẹ̀ o. iPhone mi ọ̀wọ́n yára máa bọ̀ wálé o!

Comments
Post a Comment