Ìmọ́lẹ̀ l'ọkọ òkùnkùn

Ìjẹta, mọ́júmọ́ àná, ni ọjọ kọkàlélógún sí ìkejìlélógún oṣù kejìlá ọdún. Alẹ́ yìí ni alẹ́ gígùnjùlọ lọ́dún. Fún wákàtí mẹ́rìndílógún gbáko ni òkùnkùn ṣú biribiri, ìyẹn ní Ígíláàndì ní'hàhín. Ní'hà ibòmíì, ilẹ̀ ṣú fún wákàtí mọ́kànlélógún. Kódà, a rí ibi tí ilẹ̀ ò tilẹ̀ mọ́n rárá lọ́jọ́ náà. N kò fi parọ́ rárá.

Ọpẹ́lọpẹ́ iná tí kìí lọ, tí kìí dákú ní'lẹ̀ yìí. Gbogbo ojú títì a tanná niniini. Láàrin òru gan-an, gbogbo ilé ní ìgboro ìlú a tanná kalẹ̀ gbòò. Gbogbo ẹ̀ á wá mọ́nlẹ̀ dáadáa.

Pàápàá jùlọ, àsìkò tí a ti súnmọ́ àjọ̀dún kérésìmesì gbọ̀ngbọ̀n, oríṣìíríṣìí iná aláràbarà ni àwọn ará ilẹ̀ yìí fi ń ṣe ìgboro wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Yirinyirin aláràbarà ọlọ́kanòjọ̀kan ni èèyàn a máa rí níbikíbi tí èèyàn bá lọ. Ó wuyì gbáà.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?