Ìmísí ayọ̀
Yoòbá ní "Kùtù-kùtù kìí jóni lẹ́sẹ̀ bí ọ̀sán". Torí ìdí èyí, èmi a máa tètè jí ṣe oun tí mo ní ṣe lóòjọ́. Pàápàá nígbà ooru tí oòrùn máa ń tètè là ní ìlú yìí. Ojúmọ́ a ti sáré mọ́n ní nkan bí ago mẹ́fà òwúrọ̀.
Ṣùgbọ́n a ti kọjá ọjọ́dọ́gba tó síwájú ìgbà-ìwọ́wé (ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ rèé). Ajẹ́pé àwọn ewé ti bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ lórí àwọn igi.
Àpẹrẹ pé àwọn igi wọ̀nyí àti àwọn ewéko gbogbo ti ń gbáradì fún ọ̀gìnìntìn tó ń bọ̀ lọ́nà.
Ìgbà yìí a máa rẹwà púpọ̀. Àwọn ewéko a máa pa àwọ̀ dà, ewé wọn a máa pọ́n kuku, wọ́n a rí kàlákìnní.
Ṣùgbọ́n bótiwù kí òde rẹwà tó, àsìkò yí ni àmì ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń ṣábàá bẹ̀rẹ̀ sí í farahàn lára àwọn ènìà. Àwọn onímọ̀jìnlẹ̀ ni wọ́n mọn ìdí abájọ, àmọ́ àyípadà sí ètò ìlà àti ìwọ̀ oòrùn kópa nínú ìmúrẹ̀wẹ̀sìbáni yìí.
Síbẹ̀-síbẹ̀, àwọn nkankan a máa mú inú ẹni dùn. Fún àpẹrẹ, mo rí àwọn òdòdó kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ta, bótilẹ̀jẹ́pé ìgbà ìwọ́wé ni a wà yí. Mo tún rí àwọn ewé kọ̀ọ̀kan tí àwọ̀ wọ́n tanná niniini, bótilẹ̀ṣepé àwọn ewé ìyókù ti ń panná.
Eyí a máa fúnni ní ìmísí ayọ̀, a sì máa lé ìrẹ̀wẹ̀sì sí kọ̀ọ̀rọ̀. Mo kí gbogbo ẹni tó fi ìhà aríwá àgbáyé ṣe ibùgbé kú ìpalẹ̀mọ́ ọ̀gìnìntìn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé o.

Comments
Post a Comment