Ìjọba amúnisìn tuntun nbọ̀

Alágbára ni àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá nṣe nígbàkan rí. Pàápàá àwọn Aláàfin Ọ̀yọ́. Ìjọba amúnisìn sì ni wọ́n jẹ́ nígbànáà fún àwọn ẹ̀yà tó yí ilẹ̀ Yorùbá po. Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni olùṣàkóso gbogbowọn, tí wọ́n sì nsan ìsákọ́lẹ̀ fún àwọn Ọba olókìkí náà.

Ọba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá, wọ́n l'óun ló ni ilé-ayé. Ìgbà yí padà fún ẹ̀yà Yorùbá nígbà ayé ọba Arólẹ̀ àti ààrẹ ọ̀nà kakanfò Àfọ̀njá. Àìṣọ̀kan ọmọ Oòduà kó wọn lẹ́rù fún Fúlàni.
Ṣèbí tí ìyà nlá bá gbeni ṣánlẹ̀, kékèké a sì máa gorí ẹni. Nígbà tó tún yá, ọkọ̀ ojú omi tún gbé jàmbá nlá dé. Àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun kówa lọ sí oko ẹrú lẹ́hìn-ọ̀rẹhìn, wọ́n sì pín àwa ìyókù ní Afirika wẹ́lẹwẹ̀lẹ mọ́nrawa. Ìjọba òyìnbó amúnisìn náà la ò bá gbọ́njú bá, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ènìyàn pàtàkì tí wọ́n ṣe làálàá, tí wọ́n ja ìjà òmìnira takun-takun.

Bíótilẹ̀jẹ́pé òmìnira ọ̀hún gan-an ò péye, ìyẹn ni pé òmìnira ìjọba lásán ni kòsí òmìnira ọrọ̀-ajé di òní-olónìí. A bọ́ lọ́wọ́ ẹkùn bọ́ sọ́wọ́ ònì ni. Àwọn ìjọba ológun wá sọ ìṣèlú ilẹ̀ Afirika di pàsí-pàrọ̀. Wọ́n kó gbogbo ti'lé tà tán, gbogbo orílẹ̀ tí í ṣe ti adúláwọ̀ wá kó si gbèsè rẹpẹtẹ. Wọ̀bílíkí wá nyàgò fún wọ̀bìà.

Ẹnu ẹ̀ lá wà báyìí-báyìí tí aṣeni fi ṣílẹ̀kùn ẹ̀hìnkùlé fún ọ̀tá! Ọ̀tá tí wọn kò kanlẹ̀ ṣílẹ̀kùn fún gan-an, díẹ̀ díẹ̀ ni imú ẹlẹ́dẹ̀ nwọ'gbà. Wọ́n ní pánsá ò fura ó já, àjà ò fura ó jìn. Ọmọ Yorùbá, àti gbogbo adúláwọ̀ ẹgbẹ́ ẹ wa, a ti sùnlọ. A sùn gbàgbé iná táa gbé sórí òrùlé. Iná ọ̀hún ti wá ran'lé wàyí, ó ti bọ́ sára aṣọ.

Àjèjì tuntun tó wọlé yìí, bí ó ti ngbé ewúrẹ ní í gbé àgùntàn. Ẹlòmíràn kanlẹ̀ ta ilẹ̀ baba rẹ̀ fún un ni l'ówó pọ́ọ́kú. Àti baálé àti baálẹ̀ ni wọ́n nyọ̀mọ́ ọn. Wọ́n nhùwà aláìgbọ́n nítorí oun tí wọ́n ó jẹ ni wọ́n nwá. Wọ́n ti gb'owó ẹ̀yìn lọ́wọ́ àlejò. Àjèjì ti da omi síwájú rẹpẹtẹ fúnrarẹ̀. Ó ku kí ó máa tẹ ilẹ̀ tútù. Àmọ́ omi'gbóná lèyí jẹ́ lẹ́sẹ̀ ọmọ Oòduà onílé. Nítorí oun tó kọ iwájú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sẹ́lòmíì.
Èmi ò kúkú dá àjèjì yìí l'ẹ́bi. Ṣèbí ìlọsíwájú ìran àti ẹ̀yà tirẹ̀ ló nwá kiiri. Ó sì rìnnà ko ibi tí Ọlọ́run dá lọ́lá, ṣùgbọ́n tí àwọn èdá ibẹ̀ kò bìkítà rárá. Àfi kí wọ́n máa bá arawọn jà lójoojúmọ́. Kìí ṣe ẹjọ́ àlejò yìí rárá.

Ta ni yó wa tawá jí pẹ́pẹ́ kúrò lójú orun òfò yìí adúláwọ̀? Àbí ṣe ibẹ̀ làá wà tí ìjọba amúnisìn míràn á tún fi dé bí?

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!