Igbó Funfun - Apá kẹta Ìrìnkèrindò Moravia


Mo kúkú tẹnu mọ́n ọn pé Oníyanu ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn, Ó ṣ'èkan ní dúdú aró, ọ̀kan funfun gbòò bí aṣọ àlà. Ẹlòmíì a pọ́n kuku bí aṣọ àparò, Elédùà ló ní kó máa rí bẹ́ẹ̀.

Njẹ́ Aṣèyíṣèmíì ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá igi inú igbó, Ọba Lókè tún dá a bí àrà ọ̀tọ̀. Èyí tó kúrú, èyí tó ga, gbogbo wọn n'ọ́n péjọ sínú igbo, tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára Ẹlẹ́dàá wọn. Òmíì fífẹ̀ gbàràgàdà bí igi osè tó tan gbòngbò kálẹ̀ káàkiri. Àwọn wọ̀nyí kìí ṣábàá ga lọ títí. Yoòbá bọ̀ ó ni "Ẹni bá máa ga, ẹsẹ̀ rẹ̀ yó tínrín" èyí ló dífá fún igi ọ̀pẹ́ nínú igbó. Ẹ jẹ́ ká fi ìyẹn sílẹ̀ ná.

Alákọ̀wé Yorùbá, ẹni Olú Ọ̀run dá lọ́lá, mo dé ibi igbó nì tí wọ́n ń pè ní Igbó Funfun. Mo rí iṣẹ́ Ọlọ́run Ọba.

Ẹ ní kíni mo rí? Yó yẹ yín o. Ní ọ̀nà àbáwọ igbó náà, àwọn arúgbó igi tò síbẹ̀ wàlàhìhì. Ìtàn fi yé wa pé àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ láti ayé-báyé ni. Àwọ̀ wọn jẹ́ funfun nini, wọn kò sì ní ewé kankan lórí rárá. Wọ́n ní àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ fún bíi ọgọ́rùn-ún mélòóka ọdún. Àgbà igi gbáà ni wọ́n.


Igi funfun eléyìí ní tirẹ̀ mọn'rarẹ̀ lágbà. Kò ṣèṣe adìẹ funfun o. Bí atẹ́gùn ṣe ń fẹ́ ni àwọn igi náà ń fì sọ́tùn-ún sósì pẹ̀lú ẹ̀lẹ̀. Ṣé pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ ni ìṣe àgbà, òun ni ijó ọba. Bẹ́ẹ̀ náà ni nkan tó jọ ohùn kẹ́lẹ́-kẹ́lẹ́ a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn igi náà wá. Á wá dàbí pé wọ́n ń kíni káàbọ̀ sí inú igbó àwọn.

Tí èèyàn bá kọ́kọ́ wọnú igbó náà, yó rí àpẹrẹ pé ọkọ̀ a máa rin ọ̀nà tó wọnú igbó náà lọ. Ọ̀nà náà tẹ́jú pẹrẹsẹ, ó sì wọnú igbó náà lọ tààrà. Àmì ìkìlọ̀ kan ń bẹ níbẹ̀ tó wípe "Ìwọ máṣẹ yà kúrò lójú ọ̀ná yìí títí tí ìwọ yó ṣe tọ igbó yìí já o!". Èyí ṣẹ̀rù bani díẹ̀. Mo yáa tẹsẹ̀ mọ́nrìn ní tèmi, èmi adúláwọ̀ tòótọ́ :)


Lọ́gán tí mo wọnú igbó náà ni mo ṣàkíyèsí i pé àwọn igi ibẹ̀ ti pàwọ̀dà, wọn kò jẹ́ funfun mọ́n. Wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í léwé kọ̀ọ̀kan lára, bíótilẹ̀jẹ́pé irúfẹ́ igi kannáà ni àwọn pẹ̀lú àwọn funfun ti iwájú igbó náà. Ìdí ẹ̀ ni pé àwọn igi abẹwélórí wọ̀nyí ò tíì di arúgbó igi. Ojọ́-orí àwọn igi wònyí ò tíì ju nkan bíi ọgọ́rùn-ún kan ọdún lọ. A jẹ́ pé àwọn ò tíì pá lórí, wọn kò tíì h'ewú lára. Àṣé ìṣe ènìyà náà ni ìṣe igi níbìkan. Ọlọ́run tóbi.

Nígbà tó yá mo bá tún dé ibìkan tó dàbí ilẹ̀ olókùúta bákan. Àwọn igi tó hù níbẹ̀, ńṣẹ ni gbòngbò wọn lọ́pọ̀ mọ́n òkúta. Ọ̀kan ló tiẹ̀ ṣemí bí ẹ̀rín bí ẹ̀rù o. Lábẹ́ igi kan, ilẹ̀ ṣe bí orí ènìyàn kan tó lanu bí ẹní kọrin. Ó kọ́kọ́ bàmí lẹ́rù ná, ṣùgbọ́n ó tún pamí ní ẹ̀rín nígbà tó múnmi rántí orin tí olóòtú ètò Tiwa'n'tiwa Alàgbà Oyèkúnlé Azeez máa ń kọ lẹ́ẹ̀kọ̀kan. "♫ òkúta òde, gbòngbò òde, ♪ ẹ bùnwa lóde lò ò..♫


Ẹ̀rín náà ni mò ń rín tí mo fi tọ igbó náà já sí pápá kan. Bí mo ti jáde ni mò rí àwọn ẹranko méjì kan tí wọn jọ irúfẹ́ ẹṣin kan. Èyí ló fi mí lọ́kàn balẹ̀ gbáà pé ibi a wí la dé yìí o. Oko àgbẹ̀ tí mo dé tì ni mo já sí lágá. Ọlọ́run ló bámi ṣé kìí ṣèèyàn.


Bí arákùnrin àgbẹ̀ náa ti rí mi ló súré tete tọ̀ mí wá, a wá jọ pasẹ̀pọ̀ dé ibi abà rẹ̀. Ajá rẹ̀ náà ń gbọ̀nrù tẹ̀lé wa. A kí arawa ní èdè wọn. Ṣé ẹ mọ̀n pé èmí kinni yìí agbédè-gbẹ́yọ̀ ni mí. Olúmọ̀nọ́nrìn náà ni mí pẹ̀lú. Gbàrà tí a wọ abà náà ni oúnjẹ́ ṣetán àti jẹ. Ṣé Yorùbá ti kúkú ní "a kìí lẹ́ni ní mọsàn ká mun kíkan'. Orí Yoòbá ti pé tipẹ́ o jàre :)


Ẹ ṣeun o ẹ̀yin ènìyàn rere wọ̀nyí. Ẹ kú àtìlẹ́hìn mi. Olúwa á gbé yín ga o. Tí ẹ bá gbádùn àwọn ìtàn mi, ẹ má ṣàìfi èsì sílẹ̀ fún mi.
Tàbí kí ẹ tẹ̀lé mí ní @alakoweyoruba [Twitter]
Bẹ́ẹ̀ náà ẹ lè fìwé ránṣẹ́ sí mi ní alakoweyoruba@gmail.com

Ẹ padà wá láìpẹ́ fún àwọn àròkọ kan t'ọ́n ń bọ̀ lọ́nà. Nkan ń bẹ ẹ̀yin ọmọ ènìyàn!

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?