Ìgbà Ìwọ́wé

Ní ìhà àríwá aiyé, ìgbà ìwọ́wé ni a wà báyìí. Àsìkò yí ni ìgbà ooru nré kọjá lọ, tí ìgbà òtútù nbọ̀ lọ́nà. Ni dédé oṣù kéèjé ọdún ni àsìkò yìí bẹ̀rẹ̀.

Ìgbà yìí ṣe pàtàkì fún àwọn àgbẹ̀ nítorí àsìkò ìkórè ló jẹ́. Onírúirú èso àti nkan ọ̀gbìn ni wọ́n nta tí wọ́n npọ́n tí wọ́n sì nrẹ̀ ní àsìkò yìí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọ́n ní ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ní àjọ̀dún àti ìdúpẹ́ tí wọ́n máa nṣe ní àsìkò yìí. Àwọn àṣà wọ̀nyí náà ló tàn dé ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Gẹ́gẹ́ bí ayàwòrán, mo fẹ́ràn àsìkò yìí lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí bí àwọn ewé orí igi ṣe máa npa àwọ̀ dà. Gbogbo ibi tí igi bá pọ̀ sí a wá dùn ún wò gidi-gaan nítorí àwọn ewé àti èso aláràbarà t'ọ́n nbẹ lórí wọn. Tí atẹ́gùn bá fẹ́, àwọn ewé wọ̀nyí á wá máa wọ́, wọ́n á máa rẹ̀ sílẹ̀ bí ẹni pé ó nrọ̀jò ewé ni. Gbogbo àdúgbò ọ̀hún á wá rẹwà lójú dáadáa.

Àmọ́ ṣá, ènìyàn ò lè ṣàì ronú oun tí nbọ̀ lọ́nà níoripé afẹ́fẹ́ tútù ní í fẹ́. Láìpẹ́ láìjìnnà, Ọ̀gìnìntìn nbọ̀.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!