Ìdìbò ààrẹ Amẹrika

Òní lọjọ́ pé ti àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Amẹrika nyan ààrẹ orílẹ̀èdè sípò nínú ìdìbò gbogbo gbòò.
Àwọn òṣèlú tí wọ́n ndu ipò yìí pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn méjì péré ni wọ́n jẹ́ asíwájú. Ìkíní ni ààrẹ òní Barak Obama. Ìkejì ni ọ̀gbẹ́ni Mitt Romney tí í ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Massachusetts.

Èyí tó bá wù kó wọlé, pàtàkì rẹ̀ ni pé kí olúkálukú tó bá lẹ́tọ̀ọ́ ìdìbò kó jáde lọ dìbò. Pàápàá jùlọ àwọn adúláwọ̀ àti àwọn obìnrin nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ló ṣòfò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ ló ti dà sílẹ̀ kí ẹ̀tọ́ ìdìbò tó sún kan àwọn obìnrin àti àwọn adúláwọ̀ ní Orílẹ̀èdè Amẹrika.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!