Fìlà wo?

Yoòbá ní a rí ẹni tó lórí tí kò ní fìlà, a r'ẹ́ni tó ní fìlà tí kò lórí. Lọ́lá Ọlọ́run Ọba, a r'ẹ́ni tó lórí kẹ̀dẹ̀rẹ̀-kẹdẹrẹ, tó tún kó fìlà jọ bí ilẹ̀ bí ẹní.

Irúfẹ́ enítọ̀hún ni Alákọ̀wé yín. Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa ló fi fún mi kìí ṣe ènìyàn.
Ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ o, ṣèbí bí a ó ba wọ fìlà, dandan ni kó bá aṣọ mu. Àfi tí ènìyàn bá fẹ́ fi'rarẹ̀ wọ́lẹ̀ ní àwùjọ.

Ṣé ẹ mọ̀n tẹ́lẹ̀ pé ará oko ni èmi jẹ́. Èmi ò mọn kíni fáàrí tí ń lọ lóde. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará èkó ti máa ń wí fún mi -"o ò damọ̀". :)

Toò. Yoòbá bọ̀ wọ́n ní "Ajá ìwòyí là ń lé sí ehoro ìwòyí". Ajẹ́pé ẹ̀yin olólùfẹ́ alákọ̀wé.com àti òntẹ̀lé @alakoweyoruba ni màá bẹ̀ sọ́rọ̀ yí o.

Ẹ dákun fìlà wo ló ba aṣọ yìí mu jùlọ? Ati pé èwo níbẹ̀ lo wuyì jù?







Ẹ yáa tètè fún mi l'ésì o, nítorí òde tí mò ń lọ náà, àrin àwọn onífáàrí gidi ni.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?