Ewu ńlá ńbẹ nínú epo-rọ̀bì!

Lẹ́nu òní sí àná ni a gbọ́ pé iná jó àwọn agbègbè kan ní ìlú Èkó. Ní Èbúté Mẹ́ta, àwọn agbẹ́gità, àwọn oníṣòwò pákó àti àwọn ìran apẹja ni iná nlá kan tó jó lánàá ṣe ní jàmbá. Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ngbé ní abúlé kan tí wọ́n tẹ̀dó sórí omi ọ̀sà ní Èbúté Mẹ́ta. Nkan tó tún ṣeni láàánú ni pé tálíkà paraku ni gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́. Oun ìní díẹ̀ tí wọ́n tún ni, àti iṣẹ́-òòjọ́ wọn náà sì ni wọ́n ti bá iná lọ.

Kìí ṣe àkọ́kọ́ rèé ni Nàaìjíríà o. Àìmọye irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló nṣẹlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ wa. Kí ọkọ̀ méjì má tíì kọlu arawọn làá ti gbọ́ pé wọ́n gbiná wọ́n sì jóná ráú-ráú lójú òpópónà. Kí ló wá fàá? Ìbéèrè yìí ò sòro dáhùn o. Ìdí abájọ ni pé nítorí kòsí ètò ìtanná tó péye ní Naija, nṣe ni olúkálukú nlo ẹ̀rọ amúnáwá fi ṣe ìtanná fúnrarẹ̀. Nkan tí ẹ̀rọ yìí nlò ṣiṣẹ́ sì ni epo-rọ̀bì. Ajẹ́ pé àwọn ènìyàn nra epo pamọ́ silé. Ẹlòmíràn lè gbé odindi garawa epo sílé!

Ìdí míràn tí àwọn èèyàn ṣe máa ngbé adúrú epo báyìí sílé ni pé wọn kò mọ ìgbà tí epo lè tán ní ilé-epo, tí wọ́n sì máa láti ràá lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ntún un tà lówó iyebíye ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta! Tí epo bá ti wà, wọ́n á yáa rọ gbogbo ọkọ̀ àti garawa wọn kún dẹ́mú-dẹ́mú. A jẹ́ pé gbogbo àwọn agbolé ní ìlú Èkó, àti ní gbogbo Nàìjíríà lápapọ̀, kìkì epo-rọ̀bì ni. Àb'ẹ́ẹ̀ rí ewu nlá bí? Njẹ́ ó yẹ́ kí ọmọ ènìyàn máa gbé irú ìlú báyìí?

Dájú-dájú ẹ̀bi ìjọba wa ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́. Ẹ̀kíní, tí wọ́n bá pèsè ètò-ìtanná to péye ni, àwọn èèyàn ò ní nílò àti máa gbé epo sílé rárá. Ẹ̀ẹ̀kejì, tí wọ́n bá pèsè epo-rọ̀bì tó káárí gbogbo gbòò, wọ́n á yéé gbé èpò sẹ́hìn ọkọ̀ rìn. Eléyìí á dẹ́kun ọkọ̀ gbígbiná lójú títì.

Àmọ́ àwọn ọmọ Naija náà kó díẹ̀ nínú ẹ̀bi o. Oríṣìíríṣìí ìkìlọ̀ ló ti bọ́ sí etí i wọn nípa ewu tí nbẹ nínú epo-rọ̀bì, ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe ngba etí ọ̀tún wọlé ni ó ngba etí òsì jáde. Ẹni a wí fún, Ọba jẹ́ ó gbọ́. Èyí tí ò gbọ́ nṣe'rarẹ̀. Ó tó ṣe bí òwe.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!