Ẹkú ayájọ́ òmìnira Nàìjíríà
Ọjọ́ òní ló di ọdún méjìléláàádọ́ta báyìí tí Orílẹ̀ Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn ti ọba àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ni wọ́n kó ilẹ̀ Yorùbá pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà míràn bíi àwọn Igbo àti Hausa sí orílẹ̀ kannáà, tí wọ́n sì sọ wá lórúkọ "Nigeria".
Àkọsílẹ̀ tòní, ìkíni ló jẹ́. Ìkíni gbogbo ọmọ Nàìjíríà jákè-jádò nílé lóko lódò lẹ́hìn odi àti níbikíbi tó wù kí ẹ wà. Ẹkú ayájọ́ òmìnira orílẹ wa o.
Comments
Post a Comment