Ehoro àti àwọn ẹyin

Easter, tí í ṣe àjọ̀dún ikú àti àjínde Jesu fún àwọn onígbàgbọ́, ti wọlé dé. Káàkiri àgbáyé ni gbogbo onígbàgbọ́ ń ya ọjọ́ òní sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí i àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n kan Kristi mọ́n àgbélébùú. Ní ṣókí, ikú àti àjínde yìí dúró fún ìràpadà ẹ̀dá kúrò nínú ìdè ikú, àti fún ànfàní ẹ̀dá láti ní iyè àìnípẹ̀kun.

Èwo wá ni ti gbogbo àwọn ẹyin aláràbarà tí a máa ń rí káàkiri ní ìgbà àjọ̀dún yìí? Àti pé kí ló kan ehoro lọ́rọ̀ yìí? Ṣé ẹyin ni Jesu fẹ́ràn láti máa jẹ nígbà ayé ẹ̀ ni? Àbí ó gbádùn ẹran-ìgbẹ́, ìyẹn ehoro yíyan-gbẹ? Ó ṣeéṣe àmọ́ kìí ṣe ìdí abájọ rèé.

Kí ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ tó dé Úróòpù, wọ́n ní àwọn ẹ̀sìn àdáyébá tiwọn tí a lè fi wé ẹ̀sìn abọ̀rìṣà. Nígbàtí wọ́n yí ẹ̀sìn padà, kìí ṣe gbogbo àṣà wọn ni wọ́n kọ̀ sílẹ̀ rárá. A jẹ́ pé àwọn àṣà kọ̀ọ̀kan tó rọ̀ mọ́n ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ ní Úróòpù ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, nínú ẹ̀sìn àtijọ́ ni wọ́n ti jẹyọ. A lẹ̀ rí àwọn àṣà wọ̀nyí nínú ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ di òde-òní. Irúfẹ́ àṣà yìí kan ni ehoro àti ẹyin nígbà àjọ̀dún àjínde. Kódà, orúkọ àjọ̀dún yìí "Easter", òrìṣà Úróòpù kan tí í jẹ́ "Ēostre" ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ orúkọ yìí.

Ọ̀ṣun ni a lè fi Ēostre wé nínú àwọn òrìṣà Yorùbá. Òun ni òòṣà ìrọ́mọbí fún ènìà, àwọn ẹranko àti nkan ọ̀gbìn àti ewéko gbogbo. Ẹranko olókìkí ni ehoro jẹ́ nípa ọmọ bíbí. Ehoro a máa bímọ rẹpẹtẹ, lẹ́ẹ̀meèlókan lọ́dún. Nítorí ìdí èyí, ehoro jẹ́ ọ̀kan nínú ẹranko tí wọ́n máa ń fi bọ Ēostre, tí wọ́n sì máa ń fi ṣe àkàwé rẹ̀. Wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ehoro ní wọ́n máa ń bá Ēostre rìn pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹyin. Àpẹrẹ ọmọ bíbí náà ni ẹyin jẹ́. Nítorí ọmọ ní ń bẹ nínú ẹyin. Nítorí ẹ̀, ẹyin náà jẹ́ nkan àpẹrẹ Ēostre ní ìhà Úróòpù àtijọ́ tí wọ́n ti ní àṣà yìí.

Ìgbà Ìrúwé ni wọ́n máa ń ṣọdún Ēostre láyé àtijọ́. Pàápàá ní oṣù kẹta nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òòjọ́ àti òkùnkùn òru ṣe wákàtí méjìlá dọ́gba-dọ́gba. Ìgbà nkan títun ni ó jẹ́. Àwọn ewéko a yọ òdòdó, àwọn ẹranko ọ̀sìn a máa ń ṣábàá lóyún tàbí kí wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ.

Ara àjọ̀dún àti ìdúpẹ́ wọn láyé àtijọ́ fún òòṣà yìí ni erémọdé kan ti jẹyọ. Àwọn òbí a fi àwọn ẹyin pamọ sí kọ̀ọ̀rọ̀-kọ̀ọ̀rọ̀ káàkiri ibi tí àwọn ọmọdé wọn ti lè ṣàwárí wọn. Wọ́n a wá pa ìtàn fún àwọn ọmọ pé ehoro Ēostre ló kó àwọn ẹyin náà wa síbẹ̀, kí ó tó sálọ. Èyi dàbí àlọ́ àti eré ìdárayá fún àwọn ọmọdé ni. Àṣà náà sì yàtọ̀ díẹ̀ káàkiri Úróòpù, ṣùgbọ́n ṣókí ẹ nìyẹn. Àṣà yìí ni ó wá dàpọ̀ mọ́n àjọ̀dún Easter ní òde-òní, tí ó jẹ́ pé dípò àwòrán Jésù lórí àgbélébùú, àsán-an ehoro àti ẹyin aláràbarà lojú ń rí.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!