Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta

United Kingdom kìkì ọmọ Nàìjá, pàápàá ọmọ Yorùbá. Ojoojúmọ́ ni ọkọ̀ ofurufú ń kó wọn wọ̀lú lọ́gọọgọ́rùn-ún wọn. Kíni wọ́n ń wá? Àròyé pọ̀ níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká mú u lọ́kọ̀ọ̀kan ní ṣókí-ṣọ́kí.

Gbogbo wa la mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọmọ Naija ni wọ́n bí sí UK, ọ̀pọ̀ náà ló sì ti di ọmọ ìlú náà nípasẹ̀ ìwé-ìgbélùú gbígbà. Àwọn wọ̀nyí ní ẹbi àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n a máa wá bẹ̀ wọ́n wò. Ìyẹn ení.

Ọlọ́run Ọba nìkan ló mọ iye ọmọ Naija to ń lọ àwọn ilé-ìwé gíga ní Orílẹ̀èdè UK lọ́dọọdún. Àwọn wọ̀nyí náà a máa gba tẹbí-tará ní àlejò láti ìgbàdégbà. Èyun èjì.

Ẹlòmíràn kàn ṣeré wá láì ní ẹbí kankan tàbí ará nílùú ọba nì. Ód'ẹ̀ta.

Àmọ́ àwọn tí ọ̀rọ̀ mí kàn lónìí ni àwọn oníṣòwò wa. Àwọn ti wọ́n ń torí káràkátà tẹsẹ̀ bọ ìrìnàjò àràmàndà wá sí UK. Àwọn tí wọ́n ń tọwọ́ b'àpò mú owó ọkọ̀ jáde san fún ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú. Ṣé mo ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìyànjẹ owó ọkọ̀ ofurufú nígbàkan? Owó kékeré kọ́ ni àwọn èèyàn wa ń ná dà sí ìlú yìí o. Ẹ̀yin ẹ wo ọjà kan ní Lọndọn tí àwọn èèyàn wá ń ná (àwọn àwòrán nísàlè)

Ìjọba UK ni láìpẹ́, ẹnikẹ́ni láti àwọn orílẹ̀èdè mélòókan, pẹ̀lú Naijiria, tó bá fẹ́ bẹ ilẹ̀ àwọn wò, ó ní láti fí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta pọ́ùn (₦750,000) lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdánilójú pé enítọ̀hún yó padà sílé tí ọjọ́ bá pé. Wọ́n ní tí ẹni náà bá padà, àwọn yó dá owó rẹ̀ padà fún un. Àmọ́ tí ó bá tayọ ọjọ́ kan péré, owó ọ̀hún di ọ̀lẹ̀lẹ̀ tó wọnú ẹ̀kọ nìyẹn.

Ṣé wọ́n ni bí kò bá ní ìdí obìnrin kìí jẹ́ Kúmólú. Àwọn òṣèlú UK fi yé aráyé pé àwọn ọmọ orílẹ̀èdè tí àwọn kà sílẹ̀ nì, wọn kò kí ń ṣábàá fẹ́ padà sílé lẹ́hìn tí àkókò tí a fún wọn ba tán. Gbogbo ènìyàn tí ọ̀rọ̀ yìí bà ké gbànjarè. Wọ́n ní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni ìjọba UK fi ṣe. Nítorí láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n bá wí, kò sí ilẹ̀ aláwọ̀ funfun kankan níbẹ̀. Kíá ni ìjọba Naija náà fọhùn. Wọ́n rán UK létí pé òkò tí a sọ sí igi ọ̀pẹ ni í sọ padà sí ẹni. Kò bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ ni a ò bá yọ̀ pé orí àwọn olórí wa náà ti ń pé bọ̀. Ẹ jẹ́ n mẹ́nu kúro ní bẹ̀un jàre.

Ní tèmi o, mo lérò pé ó yẹ ki àwọn oníṣòwò wa yé ná UK lemọ́-lemọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa ilẹ̀ Afirika bá arawa ṣòwò, kí a máa ra ọjà arawa kí ìlọsiwájú tó péye lè dé bá wa. Kí a yé kó gbogbo owó wa wá sí òkè òkun níbi tí wọ́n ti ń yàn wá jẹ káàkiri, tí wọ́n tún ń fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ẹ jẹ́ kí a yé fi ojú tẹ́mbẹ́lú nkan tiwa n'tiwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, irú ẹ̀gbìn yìí ò ní káwọ́ nílẹ̀ bọ̀rọ̀.
 

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!