EarPod olówó pọ́ọ́kú gbòde
Mo ti jáwọ́ lápọ̀n tí ò yọ̀ wàyí, mo ti gbómi ilá kaná. Ilá ọ̀hún sì yọ̀ bọ̀lọ̀-bọ̀lọ̀ gidi.
Ẹwo ni ká má tíì lo nkan fún oṣù kan sí méjì, kóti tètè bàjẹ́? Kiní agbórinsétí mà ló gbé ìṣe rẹ̀ dé o. Sony MDREX50LPW tí mo rà níjọ̀ọ́sí ló mà ti bàjẹ́ o. Mo tìí bọ'tí pé kí ng máa gbádùn orin lọ ni apá ọ̀tún rẹ̀ bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dákú-dájí. Ìgbà tó yá ó kúkú wá dákẹ́ pátápátá. Ówá jẹ́ etí kan péré ló ngbé ohùn sí.
Toò, kò kúkú yẹ kó yàmí lẹ́nu púpọ̀. Owó ránpẹ́ ni mo san nígbà tí mo ràá. Wọ́n dínwó rẹ̀ kù níbi tí mo ti ràá ni. Àṣé wọ́n fẹ́ tètè ta gbogbo ẹ̀ kúrò lórí igbá ni. Kò sì sọ́nà àti dá a padà mọ́ báyìí.
Èmi ò lè ṣe kí ng má máa gbọ́ àgbọ́rìn o. Orin ni o, ìròhìn ní o tàbí ìwé àfetígbọ́, gbogbo ìgbà ni èmi máa ngbọ́ nkan ní tèmi. Nítorínáà, mo yára sáré lọ sí ilé-ìtajà Apple kan tí nbẹ láàrin ìlú. Mo ra agbórisétí tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde tí wọ́n npè ní EarPod. EarPod yìí, iPod àti iPone ni wọ́n ṣe é fún. A máa gbóhùn sétí, a sì máa gba ohùn lẹ́nù. Ìyẹn ni pé èèyàn lè fi báni sọ̀rọ̀ láì gbé ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ gan-gan sétí. Kódà èèyàn lè lòó fi darí iPhone/iPod - fi jẹ́ ìpè ago, fi yín orin sókè tàbí sílè, fi yan orin míràn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àmọ́ nkan tó ṣe pàtàkì jùlọ nípa rẹ̀ ni pé Apple fúnni ní ìdánilójú pé ti EarPod yìí bá bàjẹ́ láàrin ọdún kan, àwọn ó fúnni ní òmíran tuntun, tí àwọn ò bá lè tún un ṣe. Ilé-Iṣẹ́ yìí sì ni àdéhùn tó ṣe é gbójúlé, tó sì fúnni ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Àti pé dídárasí ati wíwuyìsí EarPod olówó pọ́ọ́kú yìí, bíi ti olówó iyebíye ni.
Toò, kí ng wá gbé orin Aṣa kan síi ojàre.

Comments
Post a Comment