Ẹ kú àṣekù ọdún o

Ẹ nlẹ́ o ẹ̀yin èèyàn mi. Báwo lẹ ṣe wọnú ọdún titun? Pẹ̀lú ìdúpẹ́ àti àdúrà àbí? Mo jẹ́rìí yín lọ́pọ̀lọpọ̀. Kòní bàjẹ́ láíláí. Àṣẹ Èdùmàrè. Ire ọdún titun á kárí gbogbo wa o. Àmín Olúwa.
Toò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi Alákọ̀wé yín tòótọ́, àwọn àwòrán tó jọjú ni mo mú wá lónìí o. Ẹ gbà'wọ̀nyí ẹ fi bẹ̀rẹ̀ ọdún titun. Ẹ̀yin tí ẹ wo àwọn àwòrán wọ̀nyí, ojú yín ò ní fọ́. Kọ̀mpútà yín ò ní gbiná nígbà kankan. Lọ́lá Ọbalókè. Èmi náà nkọ́? Ìka mi ò ní dá, kò ní ṣẹ́, kò ní gé. Ẹ̀rọ ayàwòrán mi ò ní paṣẹ́tì o. Àṣẹ Elédùà.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?